Kwara Commissioners: Àgùnbánirọ̀ obìnrin, ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n di kọmíṣọ́nnà ní Kwara

Oríṣun àwòrán, Facebook/Abdulrahaman Abdulrasaq
Gomina ipinlẹ Kwara, Alhaji Adulrahman Abdulrazaq kede awọn kọmiṣọnna tuntun lẹyin oṣu mẹfa ati aabọ ti wọn ṣe ibura fun un gẹgẹ bi gomina ipinlẹ naa.
Eyi ni awọn kọmiṣọnna ati ile iṣẹ wọn ti Gomina Abdulrazaq kede lonii ọjọ Ẹti.
Ile iṣẹ ijọba idagbasoke ọdọ ati ere idaraya
Agunbanirọ obinrin, Joana Kolo ni Gomina ipinlẹ Kwara yan gẹgẹ bi kọmiṣọnna ile iṣẹ ijọba to n ri si ọrọ idagbasoke ati ere idaraya.
- Kò sí ọkùnrin tí yóò fún obìnrin tó halẹ̀ bíi tèmi lówó - Lizzy Anjorin
- Táyà ọkọ̀ agbépo tó fọ́ fa ìjàmbá ọ̀kọ̀ l'Ékò, èèyàn kan farapa
- Boris Johnson àti ẹgbẹ́ rẹ̀ wọlé ìbò, Trump àtàwọn ààrẹ míì kíi kú oríire
- Ọdun ń lọ sópin, ariwo 'ń sọ̀ ní ilé ńlá l'Abuja
- Ẹjọ́ Sowore bọ́ sọnù lọ́wọ́ àjọ DSS
- Ẹ́ wo ojú àwọn òṣèré tíátà tó péjú sí Ibadan fún ìpàdé ọlọ́dọọdún
- Òṣìṣẹ́ INEC méjì yóò ṣẹ̀wọ̀n ọdún 21 nítorí owó ẹ̀yìn N362m
- 'Penis Fish", ẹ̀ja tuntun tó rí bí ǹkan ọmọkùnrin lùwẹ̀ jáde lórí òkun
Joana to jẹ ọmọ ọdun mẹrindinlọgbọn ni kọmiṣọnna ti ọjọ ori rẹ kere julọ kaakiri orilẹede Naijiria bayii.
Kọmiṣọnna fun iṣẹ ṣiṣe
Amoju ẹrọ Rotimi Suleiman ni kọmiṣọnna fun ile iṣẹ to n ri si ọrọ iṣẹ ṣisẹ ni ipinlẹ Kwara.
Kọmiṣọnna fun iṣẹ ṣiṣe
Dokota Raji Abdulrasaq ni yoo maa tukọ ile iṣẹ ijọba to n ri si eto ilera nipinlẹ Kwara.
Kọmiṣọnna fun ọrọ oye jijẹ ati ijọba ibilẹ
Arabinrin Aisha Patigi ni oludari tuntun fun ile iṣẹ ijọba to n ri si ọrọ oye jijẹ ati ọrọ ijọba ibilẹ ni ipinlẹ Kwara bayii.Kọmiṣọnna fun eto ọgbinHeriat Adenike ni kọmiṣọnna fun ile iṣẹ ijọba to n ṣakoso eto iṣẹ agbẹ.
Kọmiṣọnna fun ile iṣẹ idagbasoke awujọ
Deborah Bose Aremu ni gomina yan kọmiṣọnna fun ile iṣẹ to n ri si idagbasoke awujọ ni ipinlẹ Kwara.
Kọmiṣọnna fun ayika
Aliyu Mohammed ni kọmiṣọnna ti yoo maa tukọ ile iṣẹ ijọba to n mojuto ọrọ ayika nipinlẹ Kwara.
Kọmiṣọnna fun eto ẹkọ
Arabinrin Fatimah Bisola ni kọmiṣọnna tuntun fun ile iṣẹ ijọba to n ri si eto ẹkọ.
Kọmiṣọnna fun eto ẹkọ ile iwe giga
Saadat Modibbo Kawu ni kọmiṣọnna fun ile iṣẹ ijọba ti yoo maa ṣamojuto ọrọ eto ẹkọ ile iwe giga ni Kwara.Kọmiṣọnna eto iṣuna
Olasunbo Florence ni kọmiṣọnna tuntun eto inawo
Kọmiṣọnna eto idajọ
Amofin Ayinla Jawondo ni kọmiṣọnna eto idajọ nipinlẹ Kwara.
Kọmiṣọnna ohun amuṣagbara
Aliyu Moro Sabi ni Gomina ipinlẹ Kwara yan gẹgẹ bi kọmoṣọnna ohun amiṣagbara.Kọmiṣọnna oko-owoỌgbẹni Agbaje wahab lo jẹ kọmiṣọnna fun ile iṣẹ ijọba to n ri si ọrọ oko owo.
Kọmiṣọnna eto ibaraẹnisọrọMurtala Olarenwaju ni kọmiṣọnna tuntun fun ile iṣẹ ijọba to n ṣamojuto ibaraẹnisọrọ.
Kọmiṣọnna ohun elo omi
Arinola Lawal lo jẹ kọmiṣọnna fun ile iṣẹ ijọba to n ṣamojuto ohun elo omi mimu nipinlẹ Kwara.
Kọmiṣọnna iṣẹ akanṣe
Arabinrin Funke oyedun Juliana ni kọmiṣọnna tuntnun fun ile iṣẹ ijọba to n ṣakoso akansẹ iṣẹ.












