Election fraud: Òṣìṣẹ́ INEC méjì yóò ṣẹ̀wọ̀n ọdún mọ́kànlélógún fún gbígba rìbá N362m

Awọn oṣiṣẹ INEC kan n gbaradi fun iṣẹ

Oríṣun àwòrán, InEC

Eto idibo ọdun 2015 ti waye o ti lọ, koda eto idibo miran ti waye lẹyin rẹ ni ọdun 2019; ṣugbọn fun awọn oṣiṣẹ ajọ eleto idibo INEC meji kan, iya wọn ṣẹṣẹ bẹrẹ ni o.

Oṣiṣẹ ajọ INEC ni Ibrahim Mohammed ati SahaboIya-Hamman lasiko idibo ọdun 2015, amọṣa awọn mejeeji ti ri ẹwọn ọdun mọkanlelogun he bayii fun gbigba riba ti owo rẹ to ọdunrun o le ọgọta ati meji miliọnu naira (N362m) lasiko idibo naa.

Àkọlé fídíò, Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n Yorùbá foríkorí gbé ìwé tó lè sọ ẹ̀yà ara yín lédè Yorùbá.

Ajọ to n gbogun ti iwa ijẹkujẹ lorilẹede Naijiria, EFCC lo gbe awọn mejeeji yii lọ si ile ẹjọ pẹlu minisita fun ọrọ epo rọbi tẹlẹ lorilẹede Naijiria, Arabinrin Diezani Alison-Maduekwe lasiko idibo ọdun mẹrin sẹyin lori owo ti iroyin sọ pe wọn gba lọwọ rẹ.

Amọṣa, wọn ko tii ri arabinrin Diezani mu bayii.

Ninu idajọ rẹ to gbe kalẹ ni ile ẹjọ giga kan ni ilu Yola, ipinlẹ Adamawa, Onidajọ Nathan Musa ni pẹlu ẹri awọn ẹlẹri marundinlogun to yọju niwaju ile ẹjọ naa ati esi awọn olujẹjọ naa, o fihan pe wọn jẹbi ẹsun naa.

Àkọlé fídíò, Naira Marley: Adọ́jọ́ ṣún ìgbẹ́jọ́ síwájú di oṣù kejì ọdún 20202

O ni o daju gbangba pe wọn gba owo riba naa, ida marun ninu ọgọrun inu rẹ ni wọn pin fun awọn oṣiṣẹ yoku ti wọn ko si lee sọ bi wọn ṣe na iyoku.

O ni ẹwọn ọdun meje-meje ni wọn yoo fara gba lori ọkọọkan ẹsun mẹtẹẹta ti wọn fi kan wọn bẹẹni ọwọ kan naa ni wọn yoo maa ṣe ẹwọn gbogbo ẹsun naa si. Iyẹn tums si pe, lẹyin-o-rẹyin ọdun meje ni wọn yoo lo lẹwọn, ṣugbọn ọdun mọkanlelogun ni yoo ka fun wọn ninu akọsilẹ.