UK Election 2019: Boris Johnson kéde pé January ni UK yóò fi EU sílẹ̀

Boris Johnson

Oríṣun àwòrán, Boris Johnson

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi, Boris Johnson ati ẹgbẹ osẹlu rẹ, Conservatives lo jawe olubori ninu idibo gbogbogbo to waye lọjọbọ nilẹ naa.

Ọgbẹni Johnson ti ṣepade pẹlu Ọbabinrin ilẹ Gẹẹsi, Queen Elizabeth lati gba iyọnda ko le fi ijọba tuntun lọlẹ.

Johnson ti sọrọ akin lẹyin to jawe olubori tan, o ni laisi ani-ani, oun ṣetan lati mu ilẹ Gẹẹsi kuro ninu ninu ajọ EU loṣu to n bọ.

Ọpọ olori orilẹede ninu ajọ EU bakan naa ti sọ pe, o dara bi ọrọ BREXIT ti n yanju bọ diẹdiẹ.

Awọn aarẹ agbaye n ki Johnson ku oriire

Ẹwẹ, awọn olori orilẹede kaakiri agbaye naa ti n sọrọ lori wiwọle Johnson ati ẹgbẹ oṣelu Conservatives ninu idibo ọjọ Ẹti.

Aarẹ ilẹ Amẹrika, Donald Trump ni orilẹede Amẹrika yoo kọwe bọwe adehun tuntun pẹlu ilẹ Gẹeṣi, lẹyin ti wọn ba dagbere fun ajọ EU tan.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Trump ni adehun yii yoo lamilaaka ju iru adehun ti wọn ti jọ ṣe tẹlẹ lọ, nigba ti wọn wa ninu ajọ EU.

Donald Trump

Oríṣun àwòrán, Reuters

Olori ijọba orilẹede Germany, Angela Merkel naa ki Johnson ku oriire, bakan naa lo sọ pe ilẹ Germany ati ilẹ Geẹṣi yoo tubọ jọ ni Narendra Modi

Olootu ijọba India, Narendra Modi naa gboṣuba fun Ọgbẹni Johnson, bakan naa lo ni oun yoo maa foju sọna fun ajọṣepọ tuntun laarin laarin ilẹ Gẹeṣi ati orilẹede India.

Minisita ọrọ ilẹ Yuropu lorilẹede Faranse, Amélie de Montchalin ni esi ibo ilẹ Gẹẹsi ti tan imọlẹ si ọrọ BREXIT.

O ni ile Franse ni lati sọrọ pọ pẹlu ilẹ Gẹẹsi bayii lori bi ajọṣẹpọ orilẹede mejeeji lati igba asiko lọ yoo ṣe ri.

Boris Johnson

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Ọgbẹni Johnson ni esi ibo naa jẹ asẹ araalu fun oun lati tete ko wọn kuro ni EU

Wo bí èsi ìdìbò UK ṣe fi hàn pé Boris Johnson ń gbégbá orókè lọ́wọ́

Gẹgẹ bi wọn ṣe n ka esi idibo ilẹ Gẹẹsi lọwọ yii, ẹkọ n foju minu han pe ẹgbẹ Conservative ni yoo jawe olubori ninu idibo naa.

Ẹgbẹ Conservative ti ni ijoko ejilelọgọtalelọọdunrun, ti awọn ẹgbẹ to ku si n du awọn ijoko to ku mọra wọn lọwọ.

Boris Johnson

Oríṣun àwòrán, Twitter/BorisJohnson

Esi yi n fi han pe o ṣeeṣe ki adari igbimọ ijọba, Boris Johnson yoo wọle lẹẹkeji.

Àkọlé fídíò, Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n Yorùbá foríkorí gbé ìwé tó lè sọ ẹ̀yà ara yín lédè Yorùbá.

Ko pẹ ti idibo naa bẹrẹ ti Johnson fi ọrọ idupẹ lede loju opo Twittter rẹ lati fun bi awọn eeyan ilẹ naa ṣe jade ni lati dibo.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Adari ẹgbẹ Labour lorilẹ-ede naa, Jeremy Corbyn ni oun ko ni dari ẹgbẹ oun ninu idibo miiran mọ, lẹyin ti ẹgbẹ Conservative fidi ẹgbẹ rẹ janlẹ.

Iroyin ni ọpọ awọn ọmọ orilẹ-ede ọhun lo jade lati kopa ninu idibo naa.

Àkọlé fídíò, Naira Marley: Adọ́jọ́ ṣún ìgbẹ́jọ́ síwájú di oṣù kejì ọdún 20202