'Penis Fish', ẹ̀ja tuntun bí ǹkan ọmọkùnrin lúwẹ̀ẹ́ jáde nínú òkun ní California

Oríṣun àwòrán, KATE MONTANA
Ẹgbẹgbẹrun awọn nkan abẹmi inu omi to fara jọ nkan ọmọkunrin ti wẹ jade sita lori omi okun kan ni ilu Carlifornia.
Awọn nkan naa to maa n ran, to lee kere pada to si lee le ri bii aran inu omi yii ni awọn onimọ sayẹnsi n pe ni Urechis caupo.
Bi o tilẹ jẹ pe mọlẹbi aran ni wọn, o wọpọ ki wọn maa pe wọn ni "ẹja Penis".
- Ṣé ẹ mọ̀ pé Ẹ̀wà Sóyà, Ẹja Puffer, àti ewébẹ̀ yìí lè ṣekú pa'ni kíákíá?
- Ìdàlúrú gbòde, ìjọba kéde ìṣéde torí nǹkan ọ̀pọ̀ ọkùnrin tó ń pòórá
- Àpanisáyé ni ẹ̀wà tí wọ́n n fí 'sniper' sí
- "Mo fi nǹkan ọkùnrin mi sínú àgádádogo fún ọ̀sẹ̀ méjì fún ìbálòpọ̀, wàhálà bá de"
- Olólùfẹ́ méjì lẹ̀pọ̀ lásìkò ìbálòpọ̀, ni wọn bá figbe ta
- Ikú ni fífi oògùn 'Paracetamol' bọ ẹran tàbí se ẹ̀wà- Iléeṣẹ́ ìlera
- Ọlọ́pàá tají padà lẹ́yìn 'Coma' oṣù mẹ́sàán, 'sack letter' làwọn ọ̀gá rẹ̀ fi kíi káàbọ̀
- Mínísítà Sunday Dare gbéná w'ojú Obasanjọ tó ní Buhari ò pèsè iṣẹ́ f'áwọn ọ̀dọ́ Nàìjíríà
Ṣe ni awọn aran maa n ri ara wọn bọ abẹ ilẹ ṣugbọn laipẹ yii ni iji wu wọn jade si ori okun Drakes ni nkan bii aadọta maili si ilu San Francisco ti wọn si kun gbogbo ilẹ.
Onimọ Sayẹnsi Ivan Parr kọwe lati ṣalaye pe lóòtọ́ awọn nkan abẹ ilẹ kan wa biirẹ lati nkan bii ọọdunrun miliọnu ọdun sẹyin ti awọn mii si maa n lo to ọdun mẹẹdọgbọn laye.
Ninu okun, awọn nkan abẹmi naa a wu ilẹ ni dedee bi ẹya ara wọn ṣe ri bii lẹta "U" ti yoo si gun daa daa.

- Aṣírí tú! A ti mọ àwọn tó ń ṣagbátẹrù Sunday Igboho àti Nnamdi Kanu nínú ìjọba - Buhari
- Ilé ẹjọ́ ju Àfáà tó ń gbé àwọ̀ Femi Adesina wọ̀ sí ẹ̀wọ̀n ọdún 28, ó tún pàdánù dúkìá
- Iléẹ̀kọ́ fásitì OAU dí títì pa lórí akẹ́kọ̀ọ́ tó gbẹ́mìí mì ní iléwòsàn fásitì
- Àwọn ọmọ Nàìjíría fẹ́ òfin Islam ju ìjọba awarawa lọ - El-Zakzaky
Awọn orukọ mii ti wọn n pe wọn to tun lee dun un gbọ leti ni "inkeeper worm" eyi ti wn ri mu latara iru igbe aye ti wọn n gbe labẹ ilẹ.
Irufẹ awọn ẹya ẹja yii mii ni eja Shark atawọn to tun n fi ẹja Penis yii ṣe ounjẹ wọn.

Kẹẹ si maa wo o, wọn ri ẹja Penis yii gẹgẹ bi ounjẹ teeyan n jẹ́. Urechis unicinctus ni eyi ti wọn ri ni Guusu Asia, ounjẹ adidun lo jẹ lawọn orilẹede bii South Korea.

















