Muinat Ilebiyi Imeko classroom collapse: Fún ọjọ́ márùn-ún, a ò rí tísà ọmọ mi tó kú kó yọjú sí wa

Àkọlé fídíò, 'Ìyà Muinat kú nígbà tó ń mu ọmú lọ́wọ́ ni èmí ìyà-ìyá rẹ̀ ń tọ́jú rẹ̀ kí ògiri kíláàsì tó wó pa á'

Iya Muinat Ilebiyi ti ku latigba to ti n mu ọyan lọwọ, ati igba naa si ni iya-iya rẹ ti bẹrẹ si ni tọju rẹ titi to fi dagba to pari ile ẹkọ alakọbẹrẹ.

BBC Yoruba de ile awọn to padanu ọmọ wọn labẹ kilaasi to wo lu oun atawọn akẹgbẹ rẹ meji mii.

Ṣaadede ni kilaasi naa wo lu awọn ọmọ to n kọ ẹkọ naa to si pa Muinat Ilebiyi loju ẹsẹ ti awọn meji to ku si farapa.

Awọn ẹbi ọmọdebinrin naa to ṣẹṣẹ wọ kilaasi onipele ikini ni Girama sọ nipa iru ọmọ to jẹ.

"O ṣi ba mi pọn omi ko to lọ si ile ẹkọ rẹ lowurọ yii koda o ni oun o pada wa pọn eyi to ku toun ba de".

Iya-iya Muinat ni nigba ti awọn ta eti gbọ nkan to ṣẹlẹ lẹnu awọn ọmọ ile ẹkọ mii, iroyin pe ogiri wo lu ọmọ kan lẹsẹ lawọn gbọ tawọn sigbera lọ si ileewe rẹ.

"A ba awọn misirẹẹsi meji taa bi wọn amọ wọn n wo wa, igba taa ni ẹyin la n ba wi ni wọn ni awọn o ki n ṣe ọga ile ẹkọ naa o, awọn naa gbọ lawọn ṣe wa".

Arabinirin Nimota Aliu ni ẹlomiran lo sọ fun awọn pe wọn ti gbee lọ sileewosan ti wọn de ibẹ ti ko tun si nibẹ.

O ṣalaye pe ọga rẹ gan ko yọju si awọn fun odidi ọjọ marun afigba ti ijọba ṣẹ ran awọn eeyan wa ti wọn wọn tilẹ ti fẹ maa pada lo to ni ọga ile ẹkọ Nasarẹti loun.

Amọ ẹlomiran tun wa baa bẹ mọlẹbi Muinat pe kin wọn gbagbe rẹ ki wọ́n fi silẹ fun Ọlọrun.