Sanusi Lamido faraya lórí àwọn tó ń pè fún pínpín ipò ààrẹ sí kùn kan

Emir tẹlẹ fun ilu Kano, Sanusi Lamido Sanusi naa ti tako asa pinpin ipo aarẹ laarin ẹkun guusu ati ariwa Naijiria.
Sanusi, ẹni to fi atako rẹ yii han lasiko to n kopa lori eto ori mohunmaworan Arise TV ni lọpọ igba `ni oun ti maa n tako ijiroro to nii se pẹlu ẹkun ti aarẹ yoo ti wa.
Aarẹ tẹlẹ fun banki apapọ ilẹ wa naa ni orilẹede Naijiria nilo aarẹ ti yoo pegede ni, lai naani ẹkun to ti wa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo okùnfà ìṣubú ìjọba alágbádá àkọ́kọ́ àti ẹ̀kọ́ fun olóṣèlú òde òní
- Àwọn òṣìṣẹ́ iléwòsàn fásitì OAU ń pa wá lọ́kọ̀ọ̀kan, ẹ gbà wá - Ẹgbẹ akẹ́kọ̀ọ́ OAU
- Ǹkan tí wọ́n kọ fún Buhari ló kà, Sunday Igboho kò ṣẹ̀ s'ófin- Ilana Omo Oduduwa
- Nǹkan ṣẹlẹ̀ l'Abuja, Ondo àti Eko lọ́jọ́ Òmìnira
- Ọmọ ìkókó yìí bẹ̀rẹ̀ ǹkan oṣù l'ọ́mọ oṣù mẹ́rin, ó tún kojú àìsàn jẹjẹrẹ ilé ọmọ
- Aṣírí tú! A ti mọ àwọn tó ń ṣagbátẹrù Sunday Igboho àti Nnamdi Kanu nínú ìjọba - Buhari
- Ilé ẹjọ́ ju Àfáà tó ń gbé àwọ̀ Femi Adesina wọ̀ sí ẹ̀wọ̀n ọdún 28, ó tún pàdánù dúkìá
- Ìwọ́de Revolution Now bẹ̀rẹ̀ ní agbègbè Ojota ní ìpínlẹ̀ Eko
- Ẹ bá wa bẹ̀ BB Naija kò bẹ̀rẹ̀ Big Mama nàá, mo ṣetán láti ṣí ara sílẹ̀ nítorí owó - Fali Werepe
- Ẹ̀bùn ayẹyẹ Òmìnira? Buhari gbẹ́sẹ̀ kúró lórí Twitter àmọ́...
"Lọpọ igba ni mo ti maa n tako ero yii, ti mo si maa n sọ pe ibi ti aarẹ ba ti jade wa ko se nnkan kan.
A ti ri awọn gomina lẹkun guusu ti wọn n ni ọdọ awọn lo yẹ ki aarẹ ti wa lọdun 2023, nigba ti awọn gomina ẹkun ariwa ni ọdọ awọn ni aarẹ yoo ti wa.
N jẹ ẹ m pe ẹnikẹni ko darukọ ohun ti wọn n fẹ?
Ohun ti gbogbo eleyi wa fun ni lati gbe ipo aarẹ fun ẹkun kan, ti eegun nla yoo si jade nibẹ.
Idi niyi to fi jẹ pe lẹyin gbogbo igbesẹ yii, wọn yoo pada fa oludije meji ti ko wulo kankan kalẹ fun Naijiria.
Amọ awọn to ba wu lati jẹ aarẹ ni ki wọn yọju sita, boya lẹkun ariwa ni tabi ni guusu Naijiria."
Sanusi Lamido Sanusi ni awọn isẹlẹ to se koko lo wa niwaju Naijiria bayii, eyiun igbesẹ kikede esi ibo lati ori ayelujara ti yoo jẹ ki esi ibo pegede amọ ti awọn eeyan kan n ta ko o.
O ni eyi tumọ si pe wọn n kede fun ilẹ Naijiria pe awọn fẹ se magomago ibo ni, ki wa lo de ti a ko panupọ maa sọrọ lori eleyi?
"Akude kansoso ta ni gẹgẹ bii orilẹede ni pe a kii ronu rara. A gbọ fa fa to ba di ọrọ pe ka wa owo lati ipasẹ isẹ oojọ.
Amọ a kii lo ọpọlọ wa, irufẹ awọn eeyan yii si lo n mu wa sere ni Naijiria.
Ẹyin ẹ sa fun emi ni aarẹ ti yoo kajuẹ lati ibikibi ni orilẹede yii, ki awa si dibo fun, kii sa se pe yoo gbe ipo aarẹ lọ si abule rẹ."
Bakan naa ni Sanusi wa bu ẹnu atẹ awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ ajafẹtọ ẹni ati ile asofin apapọ ilẹwa, to ni wọn ko mọ isẹ wọn nisẹ rara.














