Buhari on Sunday Igboho: Buhari lè sọ nípa àwọn tó ń ti Igboho lẹ́yìn, àmọ kò sọ nípa àwọn alátìlẹyìn Boko Haram

Oríṣun àwòrán, Facebook/Bashir Ahmad
Ilana Omo Oduduwa ti fesi si ọrọ ti Aarẹ Muhammadu Buhari sọ ninu ọrọ apilẹkọ rẹ to ka lati ṣe ayajọ ominira orilẹede Naijiria to pe ọdun mọkalelọgọta bayii.
Aarẹ Buhari sọ ninu ọrọ apilẹkọ rẹ pe awọn eekan lawujọ lo wa nidi ọrọ ajijagbara ilẹ Yoruba, Sunday Igboho ati olori ẹgbẹ IPOB to n pe fun idasilẹ orilẹede Biafra, Nnamdi Kanu ti wọn fi n ṣe bo ṣe wu wọn.
Aarẹ ni ọkan lara awọn ọmọ ile aṣofin agba l'Abuja gan an wa lara awọn to n ṣe agbatẹru fun Igboho ati Kanu.
- Aṣírí tú! A ti mọ àwọn tó ń ṣagbátẹrù Sunday Igboho àti Nnamdi Kanu nínú ìjọba - Buhari
- Buhari fún ọmọ Naijiria lẹ́bùn ayẹyẹ òmìnira? Ó gbẹ́sẹ̀ kúró lórí Twitter àmọ́...
- Nàìjíríà kàn takú ni, ẹ ò páàsì, ẹ ò féèlì, ẹ ò kúrò ní kíláàsì kan náà - Àwọn ọ̀dọ́
- Ǹ jẹ́ o mọ àwọn èèyaǹ wọ̀nyí tó jà fún òmìnira Nàìjíríà?
- Wo ìṣẹ̀lẹ̀ márùn-ún tí kò bá sọ Nàíjíríà s‘ógun abẹ́lé kejì
- Ẹnikẹ́ni tí kò bá ní káàdì NIN kò ní gba ''passport'' àti ìwé-àṣẹ ìwakọ̀ ní Nàìjíríà- NCC
- Ẹ kú oríire oo! Ìjọba Nàìjíríà buwọ́lù ìsinmi ọwọ́ lómi ọlọjọ́ 14 fáwọn bàbá ikoko tuntun
- Ọmọ ìkókó yìí bẹ̀rẹ̀ ǹkan oṣù l'ọ́mọ oṣù mẹ́rin, ó tún kojú àìsàn jẹjẹrẹ ilé ọmọ
O ni bi ọwọ ṣe tẹ Igboho ati Kanu ti tu aṣiri awọn to n ṣe atilẹyin fun awọn mejeeji.
Buhari ni ijọba oun yoo fi ọwọ ofin mu gbogbo awọn to n ṣagbatẹru awọn to n beere iyapa kuro lara Naijiria tabi sọ ọrọ alufansa kiri.
Amọ, nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, agbẹnusọ fun ẹgbẹ Ilana Omo Oduduwa, Maxwell Adeleye ni ohun ti wọn kọ fun Aarẹ Buhari lo ka jade.
Ọgbẹni Adeleye ni Igboho ko ṣẹ si ofin lọna kọna, ileẹjọ gan an si ti sọ bẹẹ.
''Bibeere fun idasilẹ Yoruba ti Ilana Omo Oduduwa n ṣagbatẹru rẹ ko lodi si ofin.
Ofin Naijiria ati ofin ajọ iṣọkan agbaye gba ohun ti a n ṣe laaye.
Niwọn igba ti a ko ba da rogbodiyan silẹ, ti a si payan, ohun ti a n ṣe ko lodi si ofin.
Ti Buhari ba sọ pe oun mọ awọn to n ṣe atilẹyin fun Igboho, ko lọ gbe wọn.
Kilode ti ijọba ko tii gbe awa ti n ṣe ifẹhonuhan Yoruba Nation lati ọjọ yii?
A ti la ijọba Buhari mọlẹ nile ẹjọ niluu Ibadan ati Abuja lori ọrọ Sunday Igboho, abi ki lo tun ku?
Nigba ti Buhari sọ pe aṣofin kan wa lara awọn to n ti Igboho lẹyin, kilode ti ko sọ awọn to n ṣagbatẹru awọn janduku agbebọn ati Boko Haram?
Ati pe o yẹ ki Buhari darukọ ọmọ ile igbimọ aṣofin agba niluu Abuja to sọ pe o n ṣagbatẹru fun Igboho.
Gbogbo eyi ti Buhari n sọ yii ko sọrọ nibẹ, awa si wa lori ẹsẹ wa lori ipe fun idasilẹ orilẹede Yoruba,'' Ọgbẹni Adeleye lo sọ bẹẹ.















