Protest On Nigeria Independence Day: Aráàlú tú ẹlẹ́wọ̀n sílẹ̀ láti fẹ̀hónú hàn lọ́jọ́ àjọdún òmìnira

Ọjọ Kinni, oṣu Kẹwaa, ọdun 2021 lo pe ọdun kọkanlelọgọta ti Naijiria gba ominira labẹ ijọba ilẹ Gẹẹsi.
Ara ọtọ ni ijọba apapọ, ijọba ipinlẹ atawọn ọmọ Naijiria fi ṣe ọdun naa kaakiri Naijiria.
Bi awọn kan ṣe n ṣe iwọde, lawọn mii n tu ẹlẹwọn silẹ, bẹẹ lawọn mi n sọ pe ko si nnkan to kan awọn pẹlu ayajọ ọjọ ominira Naijiria.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo okùnfà ìṣubú ìjọba alágbádá àkọ́kọ́ àti ẹ̀kọ́ fun olóṣèlú òde òní
- Ǹkan tí wọ́n kọ fún Buhari ló kà, Sunday Igboho kò ṣẹ̀ s'ófin- Ilana Omo Oduduwa
- Ọmọ ìkókó yìí bẹ̀rẹ̀ ǹkan oṣù l'ọ́mọ oṣù mẹ́rin, ó tún kojú àìsàn jẹjẹrẹ ilé ọmọ
- Aṣírí tú! A ti mọ àwọn tó ń ṣagbátẹrù Sunday Igboho àti Nnamdi Kanu nínú ìjọba - Buhari
- Ilé ẹjọ́ ju Àfáà tó ń gbé àwọ̀ Femi Adesina wọ̀ sí ẹ̀wọ̀n ọdún 28, ó tún pàdánù dúkìá
- Ìwọ́de Revolution Now bẹ̀rẹ̀ ní agbègbè Ojota ní ìpínlẹ̀ Eko
- Ẹ bá wa bẹ̀ BB Naija kò bẹ̀rẹ̀ Big Mama nàá, mo ṣetán láti ṣí ara sílẹ̀ nítorí owó - Fali Werepe
- Ẹ̀bùn ayẹyẹ Òmìnira? Buhari gbẹ́sẹ̀ kúró lórí Twitter àmọ́...
Diẹ lara awọn iṣẹlẹ manigbagbe to waye lasiko ayẹyẹ ominiria Naijiria lọdun yii ree.
Abuja
Nilu Abuja, Aarẹ Muhammadu Buhari kọkọ ba awọn araalu sọrọ ni kutu hai ọjọ ominira, lara awọn ohun to mẹnuba ni akitiyan ijọba rẹ lati yanju ọrọ eto abo to mẹhe ati eto ọrọ aje.
Bakan naa ni ni Aarẹ tun gbẹsẹ kuro lori ofin to ti fi de oju opo Twitter, bo tilẹ jẹ pe o fi awọn ikilọ kan tẹ nidi.
Ni gbagede Eagles Square ni Abuja yii ka naa ni ijọba apapọ ti ṣe ajọyọ ọdun ominira naa ti oniruru ẹlẹgbẹjẹgbẹ si dabira nibẹ, bẹẹ naa ni awọn ọmọ ogun yan fanda lati yẹ Naijiria si.
Ni Abuja yii kan ni awọn ẹgbẹ ajafẹrọ ọmọniyan, Revolution Now ti ṣe iwọde tako ijọba Aarẹ Buhari, ṣugbọn awọn ọlọpaa fi afẹfẹ tajutaju tu awọn eeyan naa ka.
Ipinlẹ Eko
Iwọde ni awọn eeyan kan ni ipinlẹ Eko fi sami si ayẹyẹ ọdun ominira Naijiria.
Awọn oluwọde naa sọ pe awọn n wọde lodi si ijọba to wa lode nitori aye ko dẹrun fun awọn araalu lasiko ijọba ọhun.
Nibi iwọde naa ni awọn ọdọ to wa nibẹ ti sọ pe ki ijọba ṣe atunto Naijiria tabi ki Aarẹ fi ipo silẹ, iwọde naa si lọ ni pẹlẹ kutu.
Ipinlẹ Ondo
Gomina Rotimi Akeredolu ti ipinlẹ Ondo ti forijin awọn ẹlẹwọn mejidinlogun to wa lọgba ẹwọn kaakiri ipinlẹ ọhun.
Bakan naa ni Akeredolu tun yi idajọ iku awọn ẹlẹwọn kan pada si ẹwọn gbere.
Agbẹnusọ gomina ọhun, Richard Olatunde sọ ninu atẹjade kan pe Akeredolu gbe igbesẹ yii lati sami si ayẹyẹ ọdun kọkanlelọgọta ti Naijiria gba ominira.














