Revolution Now bẹ̀rẹ̀ ní agbègbè Ojota ní ìpínlẹ̀ Eko

Iwọde ti bẹrẹ ni agbegbe Ojota nipinlẹ Eko, nibi ti awọn ọdọ kan ti fi ẹhonu han tako ijọba Naijiria.
Ni nkan bi aago mọkanla owurọ ni iwọde naa bẹrẹ, pẹlu awọn akọle loriṣiriṣi lọwọ awọn oluwọde.
Ṣaaju ni iru iwọde naa ti waye ni ilu Abuja lowurọ kutu ọjọ kinni, oṣu Kẹwaa. Ṣugbọn awọn ọlọpaa fi afẹfẹ taju-taju tu wọn ka.

- Aṣírí tú! A ti mọ àwọn tó ń ṣagbátẹrù Sunday Igboho àti Nnamdi Kanu nínú ìjọba - Buhari
- Ẹ̀bùn ayẹyẹ Òmìnira? Buhari gbẹ́sẹ̀ kúró lórí Twitter àmọ́...
- Ǹ jẹ́ o mọ àwọn èèyaǹ wọ̀nyí tó jà fún òmìnira Nàìjíríà?
- Wo ìṣẹ̀lẹ̀ márùn-ún tí kò bá sọ Nàíjíríà s‘ógun abẹ́lé kejì
- Ẹnikẹ́ni tí kò bá ní káàdì NIN kò ní gba ''passport'' àti ìwé-àṣẹ ìwakọ̀ ní Nàìjíríà- NCC
- Ẹ kú oríire oo! Ìjọba Nàìjíríà buwọ́lù ìsinmi ọwọ́ lómi ọlọjọ́ 14 fáwọn bàbá ikoko tuntun

Ọkan lara awọn oluwọde ọhun sọfun BBC Yoruba pe nkan ti awọn ṣaa fẹ ijọba ti ko ni ni awọn lara.
"Ki aarẹ Buhari ṣaa maa lọ la fẹ ki ẹlomiran bọ sipo. Lana alana, wọn tun pa awọn eeyan kan niha Ariwa Naijiria. A o fẹ́ ijọba to n ni wa lara mọ́".

Nibi iwọde to waye l'Eko, la ti ri awọn akọle bi "eto iwosan ati ẹkọ ọfẹ ni ipele gbogbo", "didan èlé to gun owo ina pada", "idajọ fun gbogbo awọn to kagbako lasiko iwọde EndSars".
Bakan naa ni wọn ni awọn n fẹ ki ijọba Naijiria yọnda Omoyele Sowore.


Ko pẹ ti iwọde naa bẹrẹ ni awọn ọlọpaa de sibi iwọde naa, ti wọn si kilọ fun wọn lati ma di opopona ọkọ.
Amọ, wọn ko da wọn duro lati má a ṣe iwọde.

















