Police officer sacked: Kí ló mú kí iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá já ìwé máà lọ sílé fún Ọlọ́pàá tó wà ní 'Coma' fún oṣù mẹ́sàán?

Oríṣun àwòrán, JOAN JEPTOO
Arakunrin ọlọpaa kan to dubulẹ oorun ọlọjọ pipẹ eleyi ti oloyinbo n pe ni Coma ti taji pada lati ri pe wọn ti kọwe gba iṣẹ lọwọ rẹ.
Kọnstebuuli Reuben Kimati Lel ni ẹni taa n wi yi, iṣẹlẹ naa si waye lorileede Kenya.
Ẹsun tawọn ọga rẹ nibi iṣẹ fi kaan ni pe o sa lẹnu iṣẹ lai sọ fun ẹnikankan.
Reuben gẹgẹ bi ibatan rẹ kan ṣe sọ fun BBC farapa ninu ijamba ọkọ ni gbogbo igba ti wọn fi n wa to si n gba itọju ni ile iwosan nla kan ni Kenya.
Ko si ẹni to mọ pe o wa ni ile iwosan nitori wọn o ri iwe idanimọ lara rẹ nigba ti wọn gbe digba de ile iwosan.
Lọsẹ to kọja lawọn mọlẹbi rẹ sọ pe o ṣẹṣẹ taji loju oorun ati pe awọn naa ti n wa kaakiri fọjọ pipẹ kawọn to wa mọ ibi to wa.
''A ro pe o ti ku ni nitori nọmba rẹ ko lọ lori foonu rẹ mọ.Nibẹrẹ ọdun yi, a lọ gba oku kan ni mọṣuari ti a ro wi pe oku rẹ ni''
''Nigba ti a pada ṣe ayẹwo la wa ri pe kii ṣe Reuben''
Lọjọ Kọkanlelogun oṣu Kejila ọdun 2020 ni wọn gbe Reuben lọ si ile iwosan nla Kenyatta to wa ni olu ilu Nairobi.
- Ṣé ẹ ti rí 'Penis Fish,' ẹ̀ja tuntun tó rí bí nǹkan ọmọkùnrin tó lúwẹ̀ẹ́ jáde nínú òkun rí?
- Èèmọ̀ rèé o! Bàbá yí pòórá ní ọmọ ọdún 26, ló bá déèdé yọ sí ìlú lẹ́yìn ọdún 63
- Ẹ wo ẹyẹ ayékòótọ́ tó kó olówó rẹ̀ yọ lọ́wọ́ ikú gbígbóná
- Agbẹjọ́rò méjì yọ ẹ̀sẹ́ síra wọn níwájú adájọ ó ku ẹni tí yóò yanjú ọ̀rọ̀
O farapa ninu ijamba ọkọ kan ni wọn fi gbe lọ si ibẹ.
Ko si ami idanimọ kankan lara rẹ ti ko si taji lati le ṣalaye ibi to ti n bọ tabi ẹni to jẹ.
Ni gbogbo igba yi, awọn ọga rẹ nibi iṣẹ ọlọpaa ti kọwe gba iṣẹ lọwọ rẹ ti wọn si fẹsun kan pe o sa lẹnu iṣẹ.
Koda wọn fi iwe sita pe ki wọn mu nibi kibi ti wọn ba ti ri.Nigba ti wọn wa titi ti wọn o ri lo mu ki ileeṣẹ ọlọpaa yọwọ ninu ẹsun yi.
Reuben ti taji pada ṣugbọn yatọ si pe o sọ orukọ rẹ ati pe ọlọpaa loun jẹ, ko ranti nkan to ṣẹlẹ.
Awọn ọlọpaa lagbegbe ile iwosan yi lo pada tọ awọn mọlẹbi rẹ lọ ti wọn fi mọ pe Reuben ṣi wa laye.
Ibatan rẹ Joan Jeptoo ni awọn ti sọ ireti nu pe o ṣi wa laye ki wọn to pe awọn lati wa wo nile iwosan.
"Mo ri ni ile iwosan Kenyatta ṣugbọn ko da mi mọ bẹẹ ko si ranti ẹnikankan ninu mọlẹbi rẹ''
Ile iwosan ti ni ko pada sile rẹ ni Koibatek lagbegbe Baringo nibi ti iyawo rẹ ati awọn mọlẹbi ti n tọju rẹ.
Iroyin ayọ ni pe awọn ileeṣẹ ọlọpaa ti n gbiyanju lati da pada sẹnu iṣẹ.
Ibatan rẹ to ba ileeṣẹ iwe Iroyin Daily Mail sọ ni Reuben to ti le ni aadọta ọdun n foju sọna de igba ti yoo fẹyinti lẹnu iṣẹ.


















