Saidu Abdullahi: Ó kúrò nílé lẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n, lẹyìn ọgọ́ta ọdún ló bá ṣadede yọ sí ìlú padà'

Njẹ ẹyin ti ri ibi ti eeyan ti dawati fun ọgọta ọdun ri amọ to tun ṣadede foju han pada si awọn araale rẹ?
Ọrọ yii da bii fiimu ṣugbọn kii ṣe awada rara.
Ni ilu kan ti wọn n pe ni Dakatsalle ni ijọba ibilẹ Bebeji nipinlẹ Kano, ni iroyin kayeefi yii ti ṣẹlẹ.
- Ó ṣeéṣe ká ti ẹsẹ̀ òfin bọ èsì ìbò abẹ́nú gómìnà APC l‘Osun - Aregbesola
- Ṣé lóòtọ́ọ́ ni olubi ọmọ níí ṣe pẹ̀lú àyànmọ́ ọmọ láyé?
- "Agbódegbà ní báǹkì àtàwọn míì ló wà nídìí ìdigunjalè ọkọ̀ agbówórìn n‘Ibadan"
- Mo nífẹ̀ẹ́ ìyàwó mi jú ìyá àtàwọn ọmọ mi lọ - Kolawole Ajeyemi
- Wo àwọn obìnrin tó ń bímọ láì sùn ti ọkùnrin ní àgbáyé
- Wo èròjà inú ilé márùn-ún tó ń ba èémí jẹ́, tó sì ń le fa ikú òjijì
- Kìí ṣe ẹ̀bi àwa òṣèré tíátà pé àwọn ọ̀dọ̀ ń kánjú wá owó - Mr Latin
- Wo àwọn obìnrin ''fijilanté" tí wọ́n ṣetán à ti kojú ẹnikẹ́ni ní Kano
Niṣe ni wọn tu yaya sita lati wa wo baba agbalagba kan, ti o pada wale lẹyin ọgọta ọdun ti o dawati.
Ki lo gbe Baba pada wa sile?
Ọgọta ọdun lẹyin ti Mallam Saidu Abdullahi file silẹ lẹni ọdun mẹrindinlọgbọn, ṣadede ni wọn ri to pada wale lagbalagba.
Ki ọrọ yii baa le ye wa daada, ko pẹ si igba ti Naijiria gba ominira ni o file silẹ, to si sọ fun akọroyin BBC pe ọkan oun ti n fa ile ṣugbọn oun ko ribi pada wa sile.
Akọroyin BBC Khalifa Shehu Dokaji to ṣabẹwo si idile Saidu jabọ pe awọn ọmọ, mọlẹbi, ọmọọmọ ati awọn alabagbe pe biba, lati wa ba wọn yọ pe o pada wa sile.
Nibo ni Baba ha si lati ọjọ yii?
Ilu Ibadan ni iṣẹ aje gbe Saidu Abdullahi lọ, nibi to ti n ṣe òwò Awùsá.
A tun gbọ pe iya rẹ lo gba a niyanju lati tọ ẹgbọn baba rẹ kan lọ nigba ti o wa ni ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn.
Gẹgẹ bo ti ṣe ṣalaye fun BBC, nigba aye Emir Abdullahi Bayero to jẹ baba baba Emir Kano to wa lori oye lo ni oun ti kuro nile.
Ni igba taa n sọ yii, wọn ko tiẹ ti lala pe wọn yoo da ipinlẹ Kano silẹ rara.
Iṣiro ọdun taa n wi yii wa laarin ọdun 1926 -1953.
Pupọ ninu awọn mọlẹbi lo ti sọ ireti nu, koda awọn miran ro pe o ti ku ni.
Ohun iyalẹnu kan ni pe ede ẹnu rẹ ko yipada ati pe arugbo ko ni ko ma mọ ohun to n ṣẹlẹ lawujọ.

















