Ibadan Bullion Van Robbery: Olùbádámọ̀ràn fétò àbò fún gómìnà Oyo ṣí aṣọ lójú àwọn tó ṣe onígbọ̀wọ́ ìdigunjalè ọkọ̀ agbówórìn

Oríṣun àwòrán, Screen Shot
Bi iwadii ṣe n tẹ siwaju lori idigunjale to waye ni ilu Ibadan, lagbegbe Idi Apẹ laipẹ yii, amugbalẹgbẹ lori ọrọ abo fun gomina ipinlẹ Ọyọ, Ọgbẹni Fatai Owoṣeni ti sọrọ soke nipa isẹlẹ naa.
Owoseni tii se Kọmisana ọlọpaa nipinlẹ Eko tẹlẹ, ko to fi ẹyin ti, tun jẹ ko di mimọ pe, awọn ti wọn digunjale ninu ọkọ agboworin naa ni ajọṣepọ pẹlu awọn eeyan kaakiri ẹka kan banki to ni owo naa.
Ninu ọrọ kan to sọ lori eto ori redio kan nilu Ibadan, Owoṣeni ṣalaye pe awọn to jale naa ṣeto rẹ finifini nitori o fihan pe awọn adigunjale to ṣọṣẹ naa ni anfani si awọn iroyin kan to jẹ pe iwọnba eeyan lo yẹ ko mọ.
- "Ìná tó ń ṣe àkóso ojú pópó ló dá ọkọ̀ agbówórìn dúró, tí adigunjalè fi kọ lù ú"
- Ọlọ́pàá kánkan kò ku sùgbọ́n a pa ọkan ninu àwọn tó fẹ́ já ọkọ̀ agbówórìn gbà-Ọlọ́pàá
- Mubarak, tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ ìdigunjalè Ibadan lọ ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ikú rẹ̀ - àwọn ọ̀rẹ́ kọrin arò lẹ́yìn rẹ̀
- Wo èròjà inú ilé márùn-ún tó ń ba èémí jẹ́, tó sì ń le fa ikú òjijì
- Mo nífẹ̀ẹ́ ìyàwó mi jú ìyá àtàwọn ọmọ mi lọ - Kolawole Ajeyemi
- Gboyega Oyetola borí ìbò abẹ̀nú APC láti díje ipò gómìnà Osun lẹ́ẹ̀kejì
- Wo àwọn obìnrin tó ń bímọ láì sùn ti ọkùnrin ní àgbáyé
- Wo àwọn obìnrin ''fijilanté" tí wọ́n ṣetán à ti kojú ẹnikẹ́ni ní Kano
Bẹẹ ba gbagbe, Ọjọbọ, ọjọ Kẹwa osu Keji ọdun 2022 ni isẹlẹ idigunjale nla kan waye nilu Ibadan, nibi ti awọn ole ti ko owo to wa ninu ọkọ agboworin banki kan, ti wọn si ran eeyan mẹrin sọrun ọsan gangan, to fi mọ awọn ọlọpaa meji to n tẹle ọkọ naa.
Ọpọlọpọ awọn agbodegba, to fi mọ awọn osisẹ banki to ti lọ, lo lọwọ ninu idigunjale naa:
Owoseni ni iyalẹnu lo jẹ pe awọn adigunjale naa mọ akoko gan an pato ti wọn yoo gbe owo naa, ọna ti wọn fẹ gbe owo naa gba, ati iye awọn ọlọpaa ti yoo ba owo naa rin.
"Iṣẹ idigunjale ọlọpọ agbodegba ni. Ọpọlọpọ awọn agbodegba lo lọwọ si idigunjale naa, eyi ko si yọ awọn oṣiṣẹ banki ti wọn ti gbe e kuro"
Amugbalẹgbẹ fun gomina ipinlẹ Ọyọ lori ọrọ abo naa tun ṣalaye siwaju sii pe, aimọkan lo n ṣe awọn to n sọ pe o yẹ ki awọn ọlọpaa to wa nitosi Idi Apẹ, nibi ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ doju ija kọ awọn adigunjale naa.
Gẹgẹ bi o ṣe sọ, bi awọn ọlọpaa ba ṣe bẹẹ lasiko naa, oku ti yoo sun yoo pọ ju eyi to sun lọ nitori bi awọn adigunjale naa ba ti n gbiyanju ati sa asala, aṣita ibọn yoo ba ọpọlọpọ awọn alaiṣẹ.
Wo ọpọ ẹbi ti banki to gbe owo naa jẹ:
Ọgbẹni Fatai Owoṣeni to fi ọpọ igba jẹ kọmiṣọna ọlọpaa lawọn ipinlẹ kan lorilẹede Naijiria tun ṣalaye pe awọn Banki to gbe owo naa ni ẹbi pupọ lori iṣẹlẹ idigunjale naa.
O ni ẹbi aitẹle ilana alakalẹ fun gbigbe owo rin ati ainaani ohun to yẹ ni ṣiṣe latọdọ awọn banki ti ọrọ kan, wa lara ẹbi wọn.
O ṣalaye pe: "Ara awọn Banki pẹlu ko mọ sinu ọrọ yii o. Yatọ si pe awọn agbodegba kan wa laarin wọn, gbogbo banki ni Naijiria lo ti fọwọ si adehun lori iru ọkọ ti wọn le e maa lo lati fi gbe owo.
Awọn igbimọ banki ni ibudo apapọ kan ti wọn ti maa n gbe irufẹ ọkọ bẹẹ jade. Ọkọ ayẹta lawọn ọkọ bẹẹ gbọdọ jẹ. Bakan naa, lawọn ọlọpaa to n tẹle ọkọ agboworin bẹẹ pẹlu gbọdọ wa ni ihamọra to jọju daadaa."
O ni iyalẹnu ni pe awọn banki n gbe owo ti wọn ti ṣeto adojutofo le lori pẹlu ọkọ ti kii ṣe ayẹta; bakan naa lawọn ọlọpaa to n tẹlee ọkọ naa ko wọ ẹwu ayẹta sọrun.
O ni ko yẹ ki ileeṣẹ ọlọpaa fun banki yoowu ni ọlọpaa lati ṣọ owo, laijẹ pe banki bẹẹ ba tẹle ilana to wa nilẹ fun gbigbe owo rin.
O wa fi da awọn eeyan ipinlẹ Ọyọ loju pe iwadi ti nlọ lati fi oju gbogbo awọn to lọwọ ninu iṣẹ buruku naa han sita.
Bawo ni iṣẹlẹ idigunjale naa ṣe waye?
Ọjọ́ burúkú èṣù gbomi mu ni ọjọ́bọ̀, ọjọ́ kẹwàá, oṣù kejì ọdún 2022 jẹ́ fún àwọn olùgbé ìlú Ibadan pàápàá àwọn ara Idi-Ape.
Ní ọ̀sán ọjọ́ yìí ni àwọn ìgárá ọlọ́ṣà, alọ kólóhun kígbe, ní nǹkan bí aago méjì ọ̀sán kú ìṣẹ́jú márùndínlọ́gbọ̀n, ṣe ìkọlù sí ọkọ agbówórìn ilé ìfowópamọ́ kan ní oríta Idi Ape, Iwo road, Ibadan.
Ọlọ́pàá méjì àti ara ìlú kan àti ọ̀kan nínú àwọn adigunjalè, ló bá ìṣẹ̀lẹ̀ láabi yìí lọ.
Gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ọ̀rọ̀ ṣe ojú wọn ṣe wí, iná adarí ọkọ̀ tó wà ní Idi Ape ló dá ọkọ̀ agbówórìn tó ń gbé owó lọ láti ilé ìfowópamọ́ kan lọ sí òmíràn ní agbègbè Géètì dúró lásìkò tí àwọn adigunjalè náà fi rí ààyè ṣe ìkọlù sí wọn.
Lára àwọn tí ọ̀rọ̀ náà sọjú rẹ̀ sọ fún àwọn akọ̀ròyìn pé ọkọ̀ Toyota Sienna ni àwọn adigunjalè náà fi dẹ́bùrú ọkọ̀ agbówórìn, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní dáná ìbọn yá àwọn tó wà nínú ọkọ̀ náà láì bèṣù gbẹ̀gbà.
O ní àwọn adigunjalè àti àwọn ọlọ́pàá tó tẹ̀lé ọkọ̀ agbówórìn náà kojú ìbọn síra wọn, ṣùgbọ́n tí ọwọ́ àwọn adigunjalè náà dun àwọn ọlọ́pàá nítorí àwọn adigunjalè náà pọ̀jù àwọn ọlọ́pàá lọ.
Nígbà tí wọ́n kojú ara wọn yìí, ní ìbọn ba ọlọ́pàá méjì tí wọ́n sì bá ibẹ̀ lọ sọ́run àrèmabọ̀, tí ọlọ́pàá mìíràn sì tún farapa.
Bẹẹni Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọyọ jẹ ko di mimọ pe ọlọpaa meji lo pada jade laye lẹyin ikọlu idigunja ọkọ agboworin naa.
Atẹjade kan ti alukoro ọlọpaa ni ipinlẹ Ọyọ, Adewale Oṣifẹsọ fi sita nigba naa ṣalaye pe igba ti wọn gbe awọn ọlọpaa mẹfa ati araalu meji de ileewosan ni meji ninu awọn ọlọpaa naa pada wa jade laye nileewosan.
Ṣaaju ni kọmiṣọna ọlọpaa ni ipinlẹ Ọyọ Ngozi Ọnadẹkọ ti kede lasiko abẹwo rẹ si ibi ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ lagbegbe Idiapẹ nilu Ibadan pe ko si ọlọpaa kankan to tii ku nigba naa.



















