Kolawole Ajeyemi: Kò sí ohun tó burú ti ọkọ tàbí aya bá lówó ju ara wọn lọ, kí àwọn méjèèjì ṣá ti lówó

Iya, Kolawole Ajeyemi pẹlu aya ati Toyin Abraham, aya rẹ

Oríṣun àwòrán, kolawoleajeyemi

Olorin kan nilẹ Yoruba, Chief Commander Ebenezer Obey lo kọrin kan nigba kan pe "Ninu obi ẹni ati aya ẹni, ewo lo se pataki, ewo lo se koko?"

Ninu awo orin naa si lo ti wa idahun si ibeere naa pe "A ko le fi ọrọ aya we ti obi ẹni, a ko si le fi ọrọ obi ẹni we ti aya ẹni nitori ohun ti obi le se, aya ko le se iyẹn, ohun ti aya si le se, obi ko le se iyẹn."

Sugbọn eyi ko ri bẹẹ pẹlu gbajumọ osere tiata kan, Kolawole Ajeyemi, to tun fẹ gbajugbaja osere tiata lobinrin, Toyin Abraham ni aya.

Kolawole ati Toyin Abraham si ni Ọba Oke fun ni ọmọkunrin kan, Ireoluwa ati ẹgbọn rẹ, Temitope tii se ọmọbinrin.

Ki lo de ti Ajeyemi fi fẹran iyawo rẹ ju iya rẹ lọ:

Ninu ifọrọwerọ kan to se lori ayelujara, Kolawole, lasiko to n dahun ibeere pe ko darukọ nnkan ẹyọ kan soso to nifẹ si julọ.

Ajeyemi ni ohun kan soso ti oun nifẹ si julọ ni iyawo oun laarin awọn eeyan to sunmọ oun julọ.

"Lootọ ni mo nifẹ iyawo mi, awọn ọmọ ati iya mi amọ iyawo mi ni mo nifẹ si julọ, lẹyin naa lo kan awọn ọmọ ati iya mi."

Àkọlé fídíò, Olaiya Igwe: Àwọn ọmọde tí mò ń bá ṣe ‘skit’ ló dáwó jọ fún mi nígbà tí àìsàn inú dé sí mi

Ki lo n mu inu Kolawole Ajeyemi dun julọ:

Nigba to tun n dahun ibeere pe ki lo n mu inu rẹ dun julọ, Ajeyemi ni Ọlọrun ọba nikan lo n fun ohun ni ayọ ọkan, to si n mu inu oun dun julọ.

"Idi ti Ọlọrun se maa n mu inu mi dun julọ ni pe gbogbo ohun ti mo ba beere, Ọlọrun maa n se fun mi, to si tun maa n gbọ adura mi nigba gbogbo.

Yatọ si Ọlọrun nnkan to tun maa n mu inu mi dun julọ ni iyawo mi nitori ọkọ to ba ni aya gidi ko mọ oore ti Ọlọrun se fun.

Kii se pe o wu awọn eeyan to wa nita lati maa ja, amọ ti eeyan ba si aya tabi ọkọ fẹ, wahala maa n wa.

Kii se pe emi ati iyawo mi kii ja amọ o maa n mu inu mi dun laimọye igba tori pe iywao gidi ni ninu ile mi.

Bi eeyan ba fẹ aya tabi ọkọ rere, ohun gbogbo maa n lọ deede, bakan naa ni awọn ọmọ maa n mu inu mi dun pẹlu iya atawọn ololufẹ mi."

O wa salaye pe iya oun maa n salaye pe kii se gbogbo eeyan ni yoo ni ọkọ tabi iyawo, ti ẹru ọrọ naa si maa n ba oun.

Tọkọtaya to ba n lu ara wọn le fi ara wọn silẹ:

Bakan naa ni osere tiata naa ni gbogbo awọn lọkọlaya to ba n fi igbaju igbamu se ounjẹ lojoojumọ le fi ara wọn silẹ, ki koowa lọ ni ọtọọtọ.

"Ti o ba di pe wọn n na ara wọn ni ojoojumọ, to ba seese, o yẹ ki iru tọkọ taya bẹẹ fi ara wọn silẹ.

Eyi dara ju dipo ki wọn pa ara wọn sinu ile lọ nitori ifẹ kii binu, ja tabi yan odi amọ ti ija ba wa, ti wọn ba ti ba wọn sọ, o yẹ ko tan sibẹ ni.

Arẹmaja ko si, ajamarẹ nikan ni ko sunwọn, Ọlọrun nikan lo pe, oun nikan si lo maa n se deedee."

Àkọlé fídíò, Murphy Afolabi: Kò dùn mí tí wọn bá ṣe yẹ̀yẹ́ mi torí mò fi sí pe ṣí, èdè Osogbo ìlú mi ni

Bi ko ba si owo, ko si ifẹ:

Gbajumọ osere tiata naa tẹsiwaju ninu ifọrọwerọ naa pe ti ko ba ti si owo, ko si ohun to n jẹ ifẹ.

O ni bi ọkọ ba ni owo, aya rẹ naa gbọdọ ni nitori wọn yoo dijọ maa ran ara wọn lọwọ ni.

"Bi ọ̀kan ba ni, ti ekeji ko ni, wahala yoo maa wa ni ojoojumọ ni, bẹẹ ni n ko fara mọ ero awọn eeyan to ni ko dara ki ọkọ ni owo ju aya lọ tabi ni idakeji.

Ko si ohun to n jẹ bẹẹ, bi aya ba ni owo ju ọkọ lọ, tabi ti ọkọ ba ni owo ju aya lọ, ko si eyi ti ko dara.

Ohun to ja julọ ni ki awọn mejeeji sa ti ni owo, ẹnikẹni ninu wọn ni owo tiẹ le ju ti ẹnikeji rẹ lọ.

Ti awọn mejeeji ba ti n ran ara wọn lọwọ, wọn yoo dijọ maa ni owo si ni, ohun to se koko julọ ni ifẹ."

Àkọlé fídíò, Femi Branch: Gbogbo dúkìá mi àti ti ìyá mi ni mo tà láti tọ́jú ẹsẹ̀ mi fún ọdún méjì

Ki awọn obi mase hu iwa aidaa loju awọn ọmọ:

Ni akotan ọrọ rẹ, Kolawole Ajeyemi wa gba awọn obi nimọran lati mase maa hu iwa aidaa loju awọn ọmọ ti wọn ba bi.

"Iwọ to n fa siga, mase maa fa siga loju ọmọ nitori ọmọ naa maa fa.

Iwọ to n mu ọti ninu ile, se o n kọ ọmọ rẹ lati maa mu ọti ni, o le lọ sita lati maa lọ mu ọti rẹ.

Bakan naa ni ko dara ki awọn obi maa ja loju awọn ọmọ wọn nitori ọrọ buruku ti wọn n sọ si ara wọn, ni awọn ọmọ wọn yoo maa fi se awokọse."

Bakan naa lo tun koro oju si awọn obi to n ran awọn ọmọ wọn lati maa lọ se agbe wa fun wọn lati jẹun, pe eyi ko tọna.

O ni ọpọ awọn obi laye ode oni lo tun n joko sori ayelujara lati maa lọ tọrọ owo jẹun, eyi ti ko dara to rara.

Kolawole fikun pe o yẹ ki obi kọọkan wa isẹ se, ki wọn si tẹpa mọ isẹ, pẹlu adura, ohun gbogbo yoo lọ bo se yẹ ko lọ.

Àkọlé fídíò, Adunni Ade: Lóòtọ́ọ́ ní àwọn adarí eré máa ń ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn òṣèré-bìnrin

Ta ni Kolawole Ajeyemi:

Gbajugbaja osere tiata ni Kolawole Oluwasegun Ajeyemi ni ọpọ eeyan mọ si Awilo.

Ọjọ Kẹtadinlogun osu Kinni ni ọjọ ibi osere tiata naa, tii se ọmọ bibi ilu Ogbomoso, to si ti le ni ẹni ogoji ọdun.

Ajewole, to ti gba ọpọ ami ẹyẹ ninu isẹ tiata lo se igbeyawo pẹlu gbajumọ osere tiata miran, Toyin Abraham.

Ọlọrun si fun awọn mejeeji ni ọmọkunrin kan to n jẹ Ireoluwa bi o tilẹ jẹ pe Kolawole ti ni ọmọbinrin, Temitope, ọmọ ọdun mẹrinla kan tẹlẹ saaju igbeyawo rẹ si Toyin.

Kolawole Ajeyemi ati awọn ọmọ rẹ mejeeji, Temitope pẹlu Ireoluwa

Oríṣun àwòrán, kolawoleajeyemi