Kolawole Ajeyemi ní òun kò ṣe inúnibínu sí Toyin Abraham nítorí àṣeyọrí rẹ̀

Kolawole Ajeyemi

Oríṣun àwòrán, toyin_abraham

Gbajugbaja oṣere tiata Yoruba, to tun jẹ olowo ori Toyin Abraham, Kolawole Ajeyemi ti sọ pe kii ṣe ohun babara ti iyawo oun ba ni owo ju oun lọ.

Ajeyemi lo sọ ọrọ naa ninu ifọrọwerọ kan pẹlu ileeṣẹ iroyin abẹle Nigerian Tribune.

Gẹgẹ bii oun to sọ, bo tilẹ jẹ pe oun dagba ju Toyin Abrahama lọ lọjọ ori, ki ṣe ohun ti oju ko riri ti Toyin ba ni owo ju oun lọ.

Àkọlé fídíò, Evangelist Funmilayo Adebayo Mummy G.O: Ìgbà tí mo wà ní ìjọ́ba òkùnkùn, gbogbo ayé ló fẹ́

O ni "Ọdun 1979 ni wọn bi mi... mo si darapọ mọ iṣẹ tiata lọdun 1997 ti mo si gbagbọ pe Toyin ko tii darapọ mọ iṣẹ naa lọdun ti mo bẹrẹ iṣẹ ọhun."

"Lori ọrọ ẹni to gbajumọ julọ ninu emi ati iyawo mi, tabi ẹni to ni owo julọ, Ọlọrun lo ni owo ati ọla ni ikawọ, a si maa fun ẹnikẹni to ba wu u."

"Boya emi ni mo ni owo tabi okiki ni tabi iyawo mi, ohun to ṣe pataki ni pe awa mejeji ni a ni okiki ti a si ni owo lọwọ."

Ajeyemi ni ko ni ṣe ẹni to lowo julọ ninu awọn mejeji niwọn igba ti ẹnikan ko ba ṣe igberaga si ẹnikeji.

O ṣo pe "Kii ṣe ohun ti oju ko ri ri ti iyawo mi ba ni ọla ju mi lọ, ohun to ṣe pataki ni ki ẹnikẹni ninu awa mejeji ma ṣe igberaga si ẹnikeji nitori owo."

Àkọlé fídíò, Ọmọ ọdún mẹ́ta ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí ní lu ìlù, kí n tó di onílù Yinka Ayefele

Oṣere naa tẹsiwaju pe ko si wahala kankan laarin awọn mejeji niwọn igba ti awọn mejeji ba n ran ara wọn lọwọ.

O fi kun pe oun n sa ipa oun, oun si n ṣe daadaa nidi iṣẹ tiata ki oun to gbe Toyin ni iyawo.

Ajeyemi sọ siwaju si pe oun ni okowo ti oun ṣe, yatọ si oko nla kan ti oun tun da, nitori naa ebi ko pa oun.

O pari ọrọ rẹ pe oun ko ṣe ilara Toyin, oun ko si fi igba kankan ro ibi si ri nitori ojojumọ ni oun maa n fi adura ran lọwọ.

Lẹyin naa lo kilọ fun awọn gbọyi-ṣoyi lati dẹkun gbigbe iroyin ẹlẹjẹ kiri nipa igbeyawo oun ati Toyin.

Àkọlé fídíò, Young Tolibian