Bobrisky ní ọ̀rọ̀ àwàdà ni pé kì Ọba Benin wá fẹ́ òun

Bobrisky

Oríṣun àwòrán, Bobrisky

Gbajugba okunrin to maa n mura bi obirin, Idris Odunẹyẹ ti gbogbo aye mọsi Bobrisky ti tọrọ aforiji lọwọ Ọba ti ilu Benin, Omo N'Oba N'Edo Uku Akpolokpolo, Ewuare keji fun bi oun ṣe sọ wipe ki Ọba naa fi oun ṣe aya.

Ninu fọnran kan to fi si ori ẹrọ Instagraqm rẹ lo ti tọrọ afdoriji naa.

Bobrisky ṣalaye ninu fidio naa pe ni igba toun gun'lẹ s'ilu Benin ni oun sọ wipe ki Ọba Ewuare wa fẹ oun.

Sugbon ọrọ naa fa opọlọpọ awuyewuye ati ifẹonuhan laarin awọn ọmọ bibi ilu Benin ti wọn si bu ẹnu atẹ lu bi Bobrisky ṣe tabuku Ọba wọn.

Lẹyin igbesẹ awọn ọmọ bibi ilu Benin ọhun ni Bobrisky gba ori ẹrọ ayelujara lọ leekan sii lati tọrọ aforiji.

Bobrisky

Oríṣun àwòrán, Bobrisky

O ni alawada ni oun ati wipe oun ma n dapara lọpọlọpọ

O parọwa si Ọba Benin lati ma binu nitori awada ni oun fi ọrọ naa ṣe.

Ọpọ awọń ololufẹ rẹ lo tin fi erongba wọn lede lori ọrọ ọhun.

Àkọlé fídíò, Ọmọ ọdún mẹ́ta ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí ní lu ìlù, kí n tó di onílù Yinka Ayefele