Ọwọ pálábá ọ̀dọ́ mẹ́ta tó fẹ́ fi èèyàn ṣe òògùn owó ṣégi ní Bayelsa

Awọn ọdọ mẹta ti ọwọ ọlọpaa tẹ

Oríṣun àwòrán, others

Iroyin to tẹwa lọwọ sọ pe awọn agbofinro ti mu awọn ọdọ mẹta kan to gbiyanju lati fi eeyan se oogun owo ni agbegbe Sagbama nipinlẹ Bayelsa. Awọn afurasí naa, Emomotimi Magbisa, ọmọ ọdun mẹẹdogun, Perebi Aweke, ọmọ ọdun mẹẹdogun ati Eke Prince, ti oun naa jẹ ọmọ ọdun mẹẹdogun ni ọwọ tẹ nígbà ti wọn fẹ lo Endeley Comfort f'oogun owo. Gẹgẹ bí àwọn araadugbo ṣe wi, awọn afurasí wọn yi ti n peelo ati fi ẹni yi ṣe oogun owo ki awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ati awọn ọdọ adugbo naa to mu wọn.Iwadii fi hàn pé àwọn atilaawi yi ti pa iyè Comfort rẹ, ti wọn sì ni kí o tẹle awọn lọ sí ile ọkan ninu wọn, Emomotimi Magbisa.Nigba ti wọn dé ọdọ rẹ, wọn ge ika rẹ ti wọn sì fọn ẹjẹ rẹ soju gilaasi kan.

Àkọlé fídíò, Evangelist Funmilayo Adebayo Mummy G.O: Ìgbà tí mo wà ní ìjọ́ba òkùnkùn, gbogbo ayé ló fẹ́

Ọpelọpẹ awọn ọdọ adugbo ti ko sun lasunpara ti wọn sì n fura sí irin ẹsẹ awọn ọmọkunrin naa, lo jẹ ki ọwọ tẹ wọn.A gbọ pe wọn ko ara wọn jọ ti wọn si mu awọn afurasi yi ki wọn to fa wọn le ọlọpaa lọwọ.Alukoro ọlọpaa ni Bayelsa, Arakunrin Asinim Butswat, sọ pe awọn afurasi ọhun ti jẹwọ fawọn.Gẹgẹ bo ti ṣe wí"iwadii ti a kọkọ ṣe ti fi hàn gbangba pe awọn afurasí mẹta yi mu Comfort, ti wọn sì pa iye rẹ ki wọn to ni ko tẹle awọn kalọ sile Emomotimi nibi ti wọn ti ge ika rẹ"Komisana ọlọpaa kan saara s'awọn ọdọ adugbo naa to si ni awọn ti n ṣe iwadii bonkẹlẹ lori iṣẹlẹ naa.Ọmọdebinrin ti wọn ge ika rẹ ti n gba itọju lọwọ nile iwosan.