Ọwọ́ Ọlọ́pàá ti tẹ̀ Obìnrin ọlọ́pàá tó kí ọwọ́ ọmọ tó ń gbé pẹ̀lú rẹ̀ bọ omi gbígbóná nítorí pé o jí ẹran jẹ lásìkò ọdún Kérésìmesì

Oríṣun àwòrán, Others
Kọmíṣọ́nnà àjọ ọlọ́pàá olú ìlú ilẹ̀ wa FCT, Sunday Babaji ti pàṣẹ pé kí wọ́n fi ọwọ òfin gbé arábìnrin ọlọ́pàá kan fún ẹ̀sùn fífi ìyà jẹ ọmọbìnrin ẹni ọdún mẹ́wàá lọ́nà àìtọ́.
Wọn ni niṣe ni Ruth to jẹ ọlọpaa obinrin deede ṣe bẹẹ fun ọmọ naa látàrí pé ó jí ẹran ọdún kérésìmesì jẹ.
Arábìnrin ọlọ́pàá náà tí orúkọ rẹ ń jẹ́ Ruth ni ó dá bàǹtẹ́ ìyà fun ọmọ mọlẹbi rẹ to n jẹ Miracle ti igbe ẹkun rẹ si ta awọn ara adugbo ni olobo ti wọn si fi to agọ ọlọpaa ilu Dutse ni FCT Territory leti.
- Lẹ́yìn wákàtí mẹ́ta tí wọ́n kéde pé ìyá mi kú, ó tún mi ọwọ́ rẹ̀ ooo - Ọmọ Iyabo Oko
- Wo kókó méje tí Aàrẹ Buhari mẹ́nubà lásìkò ìfọ̀rọ̀wérọ̀ rẹ̀
- Sanwo-Olu ṣèlérí láti ṣiṣẹ́ lórí àbọ̀ ìgbìmọ̀ olùwádìí ilé alájà 21 tó wó ní Ikoyi
- Erin tẹ obìnrin kan àti ọmọ rẹ̀ pa lọ́jọ́ ọdún
- Àwọn akẹgbẹ́ Gómìnà Sanwo-Olu f'ohùn sílẹ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ìdójútini tó ṣẹlẹ̀ sí i lọ́wọ́ ọlọ́pàá ní Magodo
- Adigunjalè kọlu Kemi Afolabi, wọ́n fi àdá ṣá òun àti awakọ̀ rẹ̀
Alukoro ajọ ọlọpaa Josephine Adeh jẹrii si pe Ruth ti wa ni ahamọ awọn ọlọpaa ti iwadii si ti n lọ lori ọrọ naa.
Ruth to n gbe ni agbegbe Dutse Alhaji ni olu ilu ilẹ wa FCT ni iroyin fi ye ni wi pe o ka Miracle nibi ti o ti n ji ẹran jẹ ninu pọọtu ọbẹ.
Lọjọ aisun ọdun Keresimesi ku ọla lo ka Miracle mọ ibẹ to si fi ibinu so ọwọ rẹ mejeeji to si ko sinu omi gbona.
Awọn ara adugbo ti wọn gbọ igbe ẹkun rẹ ni wọn gbe Miracle lọ si ile iwosan Jẹnẹra Kubwa











