Is Iyabo Oko dead: Kò sí ohun tí Olorun kò lè ṣe ní àwọn ẹbí Iyabo Oko ń sọ

Iyabo Oko

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Kò sí ẹni to fé ki Obi rẹ ku laitọjọ.

Awọn ọmọ gbajugbaja oṣerebinrin ni, Sidikat Odukanmi ti ọpọ mọ si Iyabo Oko ti ba BBC Yoruba sọrọ lori ọrọ ikede iku iya wọn to gba igboro kan tẹlẹ..Lẹ́yìn wákàtí mẹ́ta tí wọ́n kéde pé ìyá mi kú, ó tún mi ọwọ́ rẹ̀ ooo - Ọmọ Iyabo Oko

Won fi imoore han si Olodumare pe o da ẹmi iya wọn pada si aaye

Wọn de n bẹbẹ fun adura gbogbo ọmọ Naijiria lasiko yii.

Skip Facebook post

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post

Lati alẹ Ọjọru, ọjọ karun-un, oṣu Kinni, ọdun 2022 ni iroyin ti n lọ lori ayelujara pe agba oṣere, Sidikat Odukanmi, ti gbogbo eeyan mọ si Iyabo Oko, ti ku.

Iroyin naa ni ọmọ rẹ ka, Bisi Aisha fi sita, eyi to tẹ BBC Yoruba lọwọ.

Iyabo Oko

Oríṣun àwòrán, Iyabo oko

Bakan naa ni osẹrebinrin, Foluke Daramola naa kọkọ kede iku rẹ ninu ọrọ kan to kọ sori Instagram rẹ, ṣugbọn to ti yọ kuro bayii.

Iroyin iku oṣere naa si ti n mu ibanujẹ ba awọn ololufẹ rẹ, ti kaluku si n daro rẹ lori ayelujara.

Ṣugbọn ṣe lootọ ni Iyabo Oko ti ku?

Kí gan-an ló n ṣẹlẹ̀ sí Iyabo Oko, ṣé lóòtọ́ ló ti kú? Ìwádìí BBC rèé

Ninu iwadii BBC ni owurọ oni, Ọjọbọ, ọjọ kẹfa, oṣu Kinni, ọdun 2022 la ti ri i pe Foluke Daramola ti pada sọ lori Instagram rẹ yii kan naa pe Iyabo Oko ṣi wa laaye.

O ni ọmọ rẹ to tufọ iku naa lo tun pada pe oun pe mama oun gbe ọwọ.

Foluke Daramola sọ pe ọmọ Iyabo to kọkọ kede iku rẹ tun ti sọ pe iya oun ko ti i kú

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Àkọlé àwòrán, Foluke Daramola sọ pe ọmọ Iyabo Oko to kọkọ kede iku rẹ tun ti sọ pe iya oun ko ti i kú

Lẹ́yìn wákàtí mẹ́ta tí wọ́n kéde pé ìyá mi kú, ó tún mi ọwọ́ rẹ̀ ooo - Ọmọ Iyabo Oko

Bakan naa ni agba osẹre miran, Toyin Adegbola, ti ọpọ mọ si Toyin Tomato naa fi sori ayelujara Instagram rẹ pe Iyabo Oko ṣi wa laye.

Pẹlu ọrọ to kọ, o jọ pe ọmọ Iyabo Oko ti kọkọ sọ fun Toyin Tomato naa pe mama oun ti ku.

Àkọlé fídíò, Young Tolibian

Ṣugbọn to tun pe pada wi pe mama oun mi ọwọ rẹ.

Toyin Tomato sọ pe "...ọmọ Iyabo Oko pe mi laipẹ yii pe o mi ọwọ rẹ, ati pe dokita ko firi eemi ninu rẹ.

Àkọlé fídíò, Lori ọrọ Olubadan tuntun

"Ọmọ yii kan naa lo kọkọ kede iku rẹ fun mi. Ẹ jọwọ, ẹ jẹ ka gbadura fun ooo."

Gbogbo iroyin tuntun yii lati ọdọ Foluke Daramola ati Toyin Adegbola ni wọn fi sita laarin oru mọju.

Toyin Tomato naa sọ pe ọmọ Iyabo to kọkọ kede iku rẹ tun ti sọ pe iya oun ko ti i kú

Oríṣun àwòrán, Screeshot

Àkọlé àwòrán, Toyin Tomato naa sọ pe ọmọ Iyabo to kọkọ kede iku rẹ tun ti sọ pe iya oun ko ti i kú

Foluke Daramola sọ pe lootọ lo ti wa nileewosan bayii.

Àkọlé fídíò, Oba Jose Dome ni Ghana

Ọmọ Iyabo Oko to kọkọ kede iku rẹ tun ti sọ pe iya oun ti ji pada

Ninu ọrọ ti oun naa kọ si ori Instagram rẹ, ọmọ Iyabo Oko, Bisi Aisha to kọkọ kede iku rẹ fun awọn oṣere meji ti a darukọ, oun naa sọ pe mama oun ko ku mọ.

"Akanda ẹda, o mi ọwọ rẹ lẹyin wakati mẹta ti wọn fidirẹ mulẹ pe o kú. Ọlọrun, titi lai la o ma yin orukọ mimọ rẹ".

Ọmọ Iyabo Oko to kee iku rẹ sọ pe mama oun tun ti ji saye pada.

Oríṣun àwòrán, Sscreeshot

Àkọlé àwòrán, Ọmọ Iyabo Oko to kee iku rẹ sọ pe mama oun tun ti ji saye pada.
Àkọlé fídíò, Big Abass gbadura ọdun tuntun fún gbogbo ololufe rẹ