Ta ni Oloye Moshood Olalekan Balogun tí àwọn Afọbajẹ mẹ́wàá nínú mọ́kànlá fẹnukò pé òun ni Olubadan ilẹ̀ Ibadan kàn?

Lekan

Oríṣun àwòrán, @LekanBalogun

Kii ṣe iroyin tuntun mọ pe Kabiyesi Olubadan ti ilẹ Ibadan, Ọba Salihu Adetunji Aje Ogugunnisọ akọkọ ti waja, ṣugbọn ohun ti o n ja ranyinranyin nilẹ bayii ni ibeere lori ẹni ti yoo rọpo rẹ.

Gbogbo agbaye lo mọ pe ara ọtọ ni ipo oye jijẹ ni ilu Ibadan, mọkanmọkan si ni.

Lekan ati Olubadan

Oríṣun àwòrán, Others

Eyi lo faa ti ọpọlọpọ awọn eeyan, yala ọmọ bibi ilu Ibadan ni tabi aare ṣe n na ika si Oloye Lekan Balogun gẹgẹ bii ẹni ti ipo naa kan.

Ọpọ to mọ Oloye Lekan Balogun lo mọ ọ gẹgẹ bii oloṣelu to fi igbakan ri jẹ sẹnetọ lorilẹede Naijiria.

Amọṣa, ki lawọn nnkan miran ti a lee sọ nipa Oloye Lekan Balogun?

Gbajumọ Oniṣowo ni Lekan Balogun to si n joko gẹgẹ bii ọmọ igbimọ iṣakoso ọpọlọpọ awọn ileeṣẹ okoowo nlanla lorilẹ-ede Naijiria ati loke okun paapaa julọ lawọn ẹka wiwa epo rọbi, iṣẹ ọgbin, karakata, iṣakoso ati irinajo afẹ.

Àkọlé fídíò, Orí Tẹlifísàn ni mo ti rí Sunday Igboho rí láyé mi, bí ìyà ṣe jẹ mi gbé láti Ibadan, dé Àtìmọ́lé DSS rèé - Ifasooto Dada

O fi igba kan ri ṣe alakaso lọpọlọpọ ẹka ni ileeṣẹ epo rọbi Shell Petroleum Development Company.

Lekan fi igba kan ri ṣe oluwadi agba ni Fasiti Ahmadu Bello, ABU to wa nilu Zaria.

Àkọlé fídíò, Ṣé o mọ̀ ipò tí ìlú Owo l'Ondo ní lórí ìtẹ́ Ile Ife? Ẹ kálọ sí ìlú mi

Lekan Balogun tun jẹ oludari nileeṣẹ iwe iroyin Triumph Newspapers to wa ni Kano; Olootu iwe iroyin oloṣooṣu -The Nigeria Pathfinder pẹlu.

O tun figba kan jẹ olubadamọran nipa akoso lawọn ileeṣẹ bii Leyland, Exite Battery ati Nigerian Breweries.

Àkọlé fídíò, Ọdún tó súnmọ́ ìdìbò ni 2022, wọ́n ó ni ta ẹ̀jẹ̀ wa sílẹ̀

Gbajumọ onkọwe, ẹlẹyinju aanu ati akọṣẹmọṣẹ ni.

O kẹkọọ gba oye imọ ijinlẹ ọmọwe, ni ẹkọ imọ akoso ilu Public Administration ni Fasiti Columbus International Universit.

Omo Balogun gboye keji Masters degree ni imọ nipa akoso ilu ati awujọ, Public and Social Adminsitration ni Brunel University.

Bẹẹ lo gboye ijinlẹ akọkọ Bscni im nipa ọrọ aje, Economics ni Fasiti Manchester University, gbogbo rẹ nilu Gẹẹsi.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Asa Ondo: Wo ìdí tí Yorùbá ṣe ń lo Ìjàpá ni olú ẹ̀dá ìtàn Àlọ́ Àpagbé- Oyelo

Ta ni Lekan Balogun ninu Oselu Naijiria?

Lojuna oṣelu, Oloye Lekan Balogun ti figba kan ri gbe igba ibo fun aarẹ lẹgbẹ oṣelu SDP.

O si tun figba kan ri gbe igba ibo gomina lẹgbẹ oṣelu PDP, bakan naa lo si tun ti di sẹnetọ ri pẹlu.

Àkọlé fídíò, Bi mo ṣe fi Ọtí, Igbó, Sìgá mímu sílẹ̀ tí mi ò kó obìnrin tó máa ń ba ayé awọn olórin jẹ́ - J.A Adelakun tó kọ orin "Amona tete

Nigba to wa ni ile aṣofin apapọ gẹgẹ bii Sẹnetọ to n ṣoju ipinlẹ Ọyọ.

Sẹnetọ Lakan Balogun jẹ alaga igbimọ tẹẹkoto lori aato Naijiria.

O si tun jẹ ọmọ ẹgbẹ awọn igbimọ tẹẹkoto lori iṣuna, abo ati ọtẹlẹmuyẹ, ọrọ ọlọpaa ati Ologun oriilẹ nile aṣofin agba Naijiria.

Àkọlé fídíò, Èmi nìkàn kọ́ ni mó n ṣe àkójọ orin- Fasoyin

Bawo ni aarin Oloye Lekan Balogun ati Oba Saliu Adetunji to waja?

Bi a ko ba ni gbagbe, Oloye Lekan Balogun wa lara awọn oloye to tẹ ori gba ade gẹgẹ bii ọba labẹ Olubadan to gbesẹ, Saliu Adetunji.

Àkọlé fídíò, Femi Babalola to n fi irin ṣe iṣẹ ọna

Lasiko iṣejọba gomina Abiọla Ajimọbi ni eyi waye.

Bẹẹ lo si fa ọpọlọpọ wahala ati gbun-gbun-gbun laarin oun ati Olubadan ana atawọn oloye bii Sẹnetọ Rashidi Ladọja.

Nigba naa ni wọn fẹsun kan Olubadan pe ijọba adaṣe lo n ṣe lai bu ọla to yẹ fun igbimọ Olubadan.

Ọpọ ọmọ Naijira lo ti n beere bayii pe igbesẹ wo lo kan lori ọrọ awọn ọba keekeeke ti oloogbe Ajimobi de ade fun nigba aye rẹ gẹgẹ bii gomina.

Bi awọn akn ṣe n sọ pe kini Oloye Lekan Balogun yoo ṣe lori rẹ nigba ti o ba gba ade gẹgẹ bii Olubadan ni awọn mii n ni apani kii fẹ ki wọn mu ida kọja lori oun ni o ṣeeṣe ki ọrọ naa ja si.

Àkọlé fídíò, 8kyti,j