Olubadan of Ibadan dead: Ààfin Olubadan sọ̀rọ̀ sókè, wọ́n ní àrùn COVID-19 kọ́ ló pa Olubadan, Saliu Adetunji- Adeola Oloko

Aworan olubadan ati ayẹyẹ itẹ rẹ

Oríṣun àwòrán, Other/bbc

Ṣe lootọ ni iroyin pe aarun coronavirus lo pa kabiyesi Olubadan, Saliu Akanmu Adetunji to jade laye?

Ibeere ti awọn eeyan kan tun n beere niyi lẹyin ti awọn ikanni iroyin kan n gbe e kiri pe arun COVID-19 lo pa ọbalaye naa.

Ṣé lóòtọ́ ni pé àrùn COVID-19 ló rán Olubadan, Saliu Adetunji re ìwàlẹ̀ àsà?

Amọṣa, aafin Olubadan ti sọrọ sita pe irọ patapata ni ọrọ yii ati pe ọlọjọ lo de fun Kabiyesi Olubadan kii ṣe atipasẹ arun COVID-19 rara.

Alagba Adeọla Ọlọkọ ṣalaye fun BBC News Yoruba pe ko si ohun to jọ ọ rara. O ni ileewosan nla UCH nilu Ibadan ni Kabiyesi ti mi eemi igbẹyin ti wọn si gbe e wale.

Aafin Olubadan

"Bi o ba jẹ pe lootọ ni pe COVID-19 lo pa Kabiyesi, UCH kii ṣe ileewosan kekere ti wọn ko ti ni sọrọ sita, bẹẹni a ko ni lee maa ṣe isin idagbere gbogbo ti a ṣe fun wọn."

Bakan naa lo tun ni awọn eeyan kan naa n gbe e kiri pe ọjọ Iṣẹgun to kọja ni kabiyesi Olubadan ti papoda.

Àkọlé fídíò, Ọdún tó súnmọ́ ìdìbò ni 2022, wọ́n ó ni ta ẹ̀jẹ̀ wa sílẹ̀

Agbẹnusọ fun olubadan ṣalaye pe musulumi ododo ni Kabiyesi Saliu Adetunji nigba aye rẹ nitori naa ko si bi wọn ṣe lee fi oku rẹ silẹ lati ọjọ Iṣẹgun laisin.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Asa Ondo: Wo ìdí tí Yorùbá ṣe ń lo Ìjàpá ni olú ẹ̀dá ìtàn Àlọ́ Àpagbé- Oyelo

Agbenuso Aafin wa rọ awọn eeyan, paapaa julọ awọn ọmọ bibi ilẹ Ibadan atawọn ololufẹ Ibadan lati maṣe tẹti si awọn iroyin ofege to n lọ kaakiri.

Àkọlé fídíò, Prophet Hezekiah New Year Prayer: Gbogbo wa ni ká ṣiṣẹ́ fún ìdàgbàsókè Naijiria