Yahoo Boys: Àwọn afurasí ọmọ Yahoo gbé òkú ọmọṣẹ́ wọn tó mu Colorado sórí afárá l'Abeokuta

Omo Yahoo

Oríṣun àwòrán, Others

Awọn afurasi onijibiti ori ayelujara ti ọpọ mọ si Yahoo boys ti n ka boro boro lagọ ọlọpaa lori iku to pa ọdọkunrin ọmọ ogun ọdun kan, Uzoma Alexander niluu Abeokuta.

Mama ọdọkunrin naa, Ogechi Alexander lo mẹjọ lọ si agọ ọlọpaa to wa ni agbegbe Adigbe pe ọmọ oun kuro nile ni ogunjo oṣu kọkanla ọdun ṣugbọn ko pada wale lati igba naa.

Uzoma ni ọmọ oun dagbere pe oun fẹ ṣe abẹwo sí awọn ọrẹ oun kan eleyii ti oun iya rẹ gan an ko mo.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi ni lati agọ ọlọpaa to wa ni Adigbe ni ọga agba ọlọpaa Ogun, CP Lanre Bankole ti pàṣẹ ki ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n ṣewadi, SCIID bẹrẹ iṣẹ lori iṣẹlẹ naa.

Oyeyemi ni DSP Nurudeen AbdulGafar at'awọn ọlọpaa mii lo mu Babatunde Owoseni ti wọn ri pọ mọ ọdọkunrin to ku naa.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Asa Ondo: Wo ìdí tí Yorùbá ṣe ń lo Ìjàpá ni olú ẹ̀dá ìtàn Àlọ́ Àpagbé- Oyelo

Oyeyemi ni Owoseni lo ran awon ọlọpaa lọwọ lati mu awọn mii bíi Azeez Oyebanji, Ayobami Adesina ati Balogun Suleiman.

'Wọn jẹwọ fun wa pé ọdọkunrin naa wa si ọdọ awọn lati koṣẹ jibiti ori kọmputa ti ọpọ mọ si "Yahoo boys."

Àkọlé fídíò, Ọdún tó súnmọ́ ìdìbò ni 2022, wọ́n ó ni ta ẹ̀jẹ̀ wa sílẹ̀

Lẹyin ti gbogbo wa jẹun tan ni a mu oogun Colorado eleyii to mu gbogbo wa sun lọ.

Nigba ti a jí laago mẹjọ ni a ri pe ọmọkunrin naa ti ku silẹ," Oyeyemi lo sọ bẹẹ.

Àkọlé fídíò, '2013 lèmi àti bàbá mi kọ́ ìlé ẹ̀kọ́ yìí fáwọn ọmọ àdúgbò torí a rántí irú ìyà tó jẹ mi ní kékeré'

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni Azeez Oyebanji to ta oògùn Colorado fun won gba wọn ni imọran pe ki wọn lọ sọ òkú ọmọkùnrin naa nu.

Oyeyemi ni Ayomide ati Gafar lo gbimọ pọ láti lò ọkọ Uber gbe oku naa lọ sori afara Kuto ni Abeokuta.

Àkọlé fídíò, 8kyti,j

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni awon oṣiṣẹ eleto ilera lo lọ gbe oku ọkunrin naa kuro lori afara ti wọn sì lọ sìn in.

Oyeyemi ni apa wa lori oloogbe naa eyi to fihan pe iwa ipa ni wọn fi ṣekupa a.

Àkọlé fídíò, Femi Babalola to n fi irin ṣe iṣẹ ọna