Gabon youth coach arrested: Olùkọ́ni ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù U-17 ní Gabon dèrò àtìmọ́lé fún ẹ̀sùn fífipá bá àwọn agbábọ́ọ́lù ọ̀kùnrin sùn

Awon agbaboolu

Olukọni tẹlẹ fun ẹgbẹ agbabọọlu Under-17 ni orilẹ-ede Gabon, Patrick Eyi, ti wa ni ahamọ ọlọpaa bayii nitori ẹsun ifipabanilopọ.

Ọjọ Ẹti to kọja ni ajọ bọọlu orilẹ-ede naa da a duro lẹnu isẹ, lẹyin ti ileeṣẹ to n mojuto ere idaraya sọ pe Aarẹ Ali Bongo ṣapejuwe ẹsun naa gẹgẹ bi eyi to lagbara pupọ.

Ọgbẹni Eyi sọ fun BBC pe oun ko jẹbi ẹsun naa. O ni ọna lati yẹyẹ awọn aṣeyọri oun ni.

Ẹsun ti wọn fi kan-an ni pe o n ni ibalopọ pẹlu awọn ọdọmọkunrin kekeeke to n dari.

Iwe iroyin The Guardian to jẹ ti ilẹ Gẹẹsi sọ pe agbabọọlu kan to wa pẹlu ikọ ọjẹ wẹwẹ nigba kan, sọ fun ohun pe iwa fifi ipa banilopọ ti n waye fun ọpọlọpọ ọdun ninu ajọ bọọlu alafẹsẹgba ni Gabon.

Agbabọọlu naa sọ pe wọn fi ipa ba oun lopọ.

Àkọlé fídíò, Odindi ọjọ́ kan ni mo fi wà ní ìhòhò ní Libya tí gbogbo èrò n fi ọwọ́ pa mí lára

Lọjọ Aiku bakan naa, wọn tun da olukọni miran duro ni Gabon lori ẹsun fifi ipa ba ọmọde lopọ.

Ẹgbẹ agbabọọlu TP Akwaenbe da Mickala Orphe duro lẹyin ti awọn eeyan fi ẹsun ifipabanilopọ kan lori ayelujara.

Àkọlé fídíò, BBC News: Ifọrọwerọ pẹlu Sẹnẹtọ Olujimi

Ni bayii, ileeṣẹ eto ere idaraya ni Gabon ti bẹrẹ iwadii lori awọn ẹsun ifipabanilopọ to n waye ninu ẹgbẹ agbabọọlu orilẹ-ede naa, to si tun sọ fun ileeṣẹ eto idajọ lati tan ina iwadii de awọn ẹka ere idaraya yooku.