African Sports Personality of the Year award: BBC kéde àwọn tó pegedé láti gba àmì ẹ̀yẹ èrè ìdárayá ọdún 2021

BBC African Sports Personality of the Year nominees

Ileeṣẹ iroyin BBC ti kede orukọ awọn eeyan to fa kalẹ fun ami ẹye ẹni to pegede julọ ninu ere idaraya lọdun 2021.

Igbimọ awọn akọroyin lati ilẹ Afrika ati ilẹ Gẹẹsi lo ṣe akojọpọ orukọ awọn eeyan mẹfa naa.

Wọn yan awọn eeyan ọhun gẹgẹ bii aṣeyọri wọn ninu awọn ifẹsẹwọnsẹ ti wọn ti kopa kaakiri agbaye laarin oṣu Kiini si oṣu Kẹsan an, ọdun 2021.

Bakan naa ni wọn tun yan awọn eeyan naa lori awọn aṣeyọri wọn yatọ si ipa ti wọn n ko ninu ere idaraya.

Awọn eeyan naa ree:

  • Eliud Kipchoge (ere idaraya)
  • Faith Kipyegon (ere idaraya)
  • Ntando Mahlangu (ere idaraya awọn akandan ẹda)
  • Christine Mboma (ere idaraya)
  • Edouard Mendy (bọọlu alafẹsẹgba)
  • Tatjana Schoenmaker (iwẹ odo)

Eliud Kipchoge

Eliud Kipchoge

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Orilẹ-ede: Kenya Ọjọ ori: 37 Ere: Ere-ije gigun

Eliud Kipchoge di gbajumọ lẹyin to jawe olubori ninu ere ije oni maili mẹrindinlogun ninu idije Olympic.

Lẹyin naa ni igbimọ Olympic naa kede orukọ rẹ gẹgẹ bii okunrin to tayọ julọ ninu idijẹ ọhun.

Okunrin ọhun jawe olubori ninu idije mẹtala ninu marundinlogun to ti kopa ninu rẹ.

Lẹni ọdun mẹrindinlogoji, Eliud Kipchoge ni okunrin to dagba julọ ti yoo bori ninu ere-ije gigun ninu idije Olympic lẹyin Calos Lopes, lati Portugal lọdun 1984.

Faith Kipyegon

Faith Kipyegon

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Orilẹ-ede: Kenya Ọjọ ori: 27 Ere: Ere-ije gigun

Faith Kipyegon bori ninu ere 1,500 mita lẹyin to ti kọkọ bori ninu ere ije naa ni Rio de Janeiro lọdun 2016.

Lẹyin to bori tan lo fi aṣeyọri naa sọ ori ọmọ rẹ obinrin to jẹ ọmọ ọdun mẹta, eyii to ni oun lo fun oun ni iwuri lati ṣe aṣeyọri.

Bo ṣe fi ami ẹyẹ naa sọri ọmọ rẹ ṣe pataki nitori oun ni elere ije kẹta ti yoo bi ọmọ, ti yoo si tun jawe olubori ninu idije lẹyin to bimọ tan.

Awọn meji akọkọ ni Shirley Strickland latri Australia ati Francoise Mbango lati Cameroon.

Ntando Mahlangu

Ntando Mahlangu j

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Orilẹ-ede: Kenya Ọjọ ori: 27 Ere: Ere-ije 200m

Ntando Mahlangu jawe olubori ninu ere idaraya awọn akandan ẹda fun igba akọkọ lasiko to wa ni ọmọ ọdun mẹrinla lọdun 2016.

Lọdun yii, o tun jawe olubori ninu ifẹwọnsẹ long jump ninu idije Olympic ni Tokyo.

Igba to wa ni ọmọ ọdun mẹwaa ni wọn ge ẹsẹ rẹ mejeji nitori ẹsẹ naa kọ lati dagbe bi awọn ẹya ara rẹ to ku ṣe n dagba.

Christine Mboma

Christine Mboma

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Orilẹ-ede: Namibia Ọjọ ori: 18 Ere: Ere-ije

Igba to wa lẹni ọdun marundinlogun lo kọkọ gba goolu fun orilẹ-ede rẹ ninu idije Tokyo Olympic 2020.

Edouard Mendy

Chelsea goalkeeper Edouard Mendy

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Orilẹ-ede: Senegal Ọjọ ori: 29 Ere: Adele bọọlu alafẹsẹgba

Edouard Mendy ti ṣe bẹbẹ lati igba to ti darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea lati Rennes.

Orukọ rẹ wọ inu iwe itan gẹgẹ bii adele ẹgbẹ agbabọọlu akọkọ lati ilẹ Afrika ti yoo kopa ninu idije Champions League.

Tatjana Schoenmaker

Tatjana Schoenmaker

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Orilẹ-ede: South Africa Ọjọ ori: 24 Ere: Breaststroke

Tatjana Schoenmaker ni obinrinn akọkọ ti yoo gba ife ẹyẹ Olympic fun South Africa lati ọdun 2000.

Nigba to ba awọn akọroyin sọrọ lẹyin to gba ami ẹyẹ naa tan, o ni afojusun oun lọwọ yii ni ki oun bẹrẹ si n ṣe daadaa ju ti tẹlẹ lọ.