Kenya Accident: Àwọn akọrin ìjọ tó fẹ́ lọ ṣe ìgbéyàwó kàgbákò òjò àrọ̀rọ̀dá, ẹ̀mí 23 sọnù...

Kenya

Oríṣun àwòrán, Citizen TV Kenya

O kere tan eniyan mẹtalelogun ti gbẹ mi mi lẹyin ti wọn ri sinu omi lasiko ti wọn n lọ fun ayẹyẹ igbẹyawo ni Kenya.

Fidio to wa ni ori ẹrọ ayelujara ṣe afihan bi omi ṣe gbe ọkọ naa lọ lasiko ti dirẹba ọkọ n gbiyanju lati gun ori afara to wa ni ori omi Enziu, ti ko jina si Nairobi to jẹ olu-ilu orilẹede Kenya.

Iroyin ni awakọ naa ati ọkọ akero naa ni wọn gba lati gbe awọn akọrin naa lọ si ibi ayẹyẹ ọhun.

Awọn mẹrin to ku jẹ ọmọde, nigba ti wọn ti doola ẹmi awọn mejila lara awọn akọrin naa

Amọ ko tii han si awọn eniyan iye ẹni to wa ninu ọkọ akero naa lasiko ti ijamba ọkọ naa ṣẹlẹ.

Iroyin ni oṣeeṣe ki awakọ naa ma mọ ọna naa daradara ati bi o ṣe le gba ori afara to wa ni Mwingi, Kitui daadaa.

Gomina agbegbe Kitui Charity Ngilu ni iṣẹlẹ naa waye ni Ọjọ Satide, opin oṣẹ.

Gomina naa fikun un pe eniyan mẹtalelogun ni wọn ri oku wọn gbe jade ninu omi, ti awọn miran si han si inu ọkọ akẹrọ.

Ijọba fikun un pe idoola ẹmi ṣi n lọ lọwọ lati doola ẹmi awọn eniyan ti wọn ha.

Ojo arọrọda ti bẹrẹ si ni rọ ni ọpọlọpọ ilu lorilẹede Kenya, to fi mọ awọn agbegbe ti aisi ojo ti fa ki iyan mu ni agbegbe naa, ti ọpọlọpọ ẹranko inu igbo si n ku ni agbegbe naa.