UK Omicron Nigeria Ban: Àwọn aṣòfin àgbà ní kí ìjọba àpapọ̀ wá ǹkan ṣe sí òfin má wọlé tí UK gbé lé Nàìjíríà

awọn aṣofin apapọ Naijiria ni gbọngan ile aṣofin

Oríṣun àwòrán, Nigeria senate/facebook

Àkọlé àwòrán, Ile ni o yẹ kí ìjọba UK wo irú ibaṣepọ to wa laarin awon mejeeji ki wọn to gbe iru igbesẹ yi ati ipa ti yóò ní lara awọn ọmọ Naijiria ti wọn n tiraka.

Ile asofin agba Naijiria naa ti dá sí ọrọ fifi orukọ Naijiria sara awọn orilẹ-ède ti ilẹ Gẹẹsi ko faaye gba lati se irin-ajo silẹ wọn nitori ẹda arun COVID-19.

Nise lawon asofin ilẹ naa bẹnu àtẹ lu igbesẹ ti ilẹ Gẹẹsi gbe gẹgẹ bí wọn ti ṣe wi:'lalae ni idi kan pataki"

Nitori naa ile aṣòfin àgbà tí wa kesi ìjọba ilẹ Gẹẹsi lati yọ orukọ Naijiria kuro ninu awọn ile ti wọn fòfin de lati ṣe Irinajo sí orileede wọn.

Ile ni o yẹ kí ìjọba UK wo irú ibaṣepọ to wa laarin awon mejeeji ki wọn to gbe iru igbesẹ yi ati ipa ti yóò ní lara awọn ọmọ Naijiria ti wọn n tiraka.

Ile ọhun wa rọ ijoba Naijiria lati fi kun lukun pelu ìjọba ilẹ Gẹẹsi lọnà ati yi ìgbésẹ yi pada.

Bẹẹ lọ ní kí ijoba ma ṣe yet lori ipinu rẹ lati ṣe ìfilọ́lẹ̀ gbogbo ilana to ba yẹ lati koju ẹda COVID-19 yi ni Naijiria.

Awọn ipinu ati imọran ile yí waye lasiko ti wọn n jiroro lori aba kan ti Seneto Ike Ekweremadu fi ṣowọ sile èyí tó dá lórí ọna ati yọ orukọ Naijiria kuro lori orukọ awọn ti ilẹ Gẹẹsi gbegi dina wọn lati wọ ilẹ rẹ.

Àkọlé fídíò, Mama Deeper Life Ondo

Ninu alaye ti ile ṣe lori ipinu yi jinle Naijiria ni orile-ede to ni iye eeyan to kere julọ to ko ẹda arun COVID-19 yi táa mọ si Omicron.

O ni igbesẹ yi yoo da eto ru paapa fawọn ọmọ Naijiria to ti n palẹmọ lati ba mọlẹbi wọn tó wà ni ilẹ Gẹẹsi se ajọdun ọdún Kérésìmesì.

Bakan naa lo ni púpọ awọn ọmọ Naijiria to ni idi pataki lati ṣe abẹwo sí ilẹ Gẹẹsi ti wọn kò fún ni iwe aṣẹ irina ni ki ni le se bẹ.

Lakotan, aṣofin Ekweremadu sọ pé kò sí ìgbà tí àwọn ọmọ Nàìjíríà kii tẹle gbogbo ilana ìdáàbòbò ti àjọ ìlera lágbayé gbe kalẹ ati eyi ti ijọba ilẹ Gẹẹsi gbe kalẹ lori arinrinajo tẹlẹ.

Ní kíákíá ẹ yí ìpinnu yín padà sí Nàìjíríà lórí ẹda ààrùn COVID-19 Omicron-Lai Mohammed

Lai Mohammed ati aworan eeyan kan pẹlu Abẹrẹ

Oríṣun àwòrán, Premium times/reuters

Ofin tẹ fi de Naijiria eyi ti kọdi awọn ọmọ ilẹ naa lati ma ṣe wọ ilẹ Gẹẹsi nitori ẹda COVID-19 jẹ idẹyẹsi ati pe ko bojumu.

Minisita iroyin ati aṣa ni Naijiria Lai Mohammed lo fi oroy yi le'lẹ lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ n'ilu Abuja.

Nítorí náà Minisita wa kesi ike Gẹẹsi lati yi ipinu padà lori aṣẹ yi ni kiakia.

Bakan naa ni wọn jiroro lori ọna abayọ lati le dẹkùn arun yi nipa fifun awọn eeyan labẹrẹ, amojuto ati ayẹwo to peye lawon ẹnu ibode abawọlu.

Ọrọ Minisita Lai yi n waye lẹyin ti Minisita feto ilera Dr Osagie Ehanire ti ṣaaju bẹnu àtẹ lu igbesẹ yi lati ọdọ ìjọba ilẹ Gẹẹsi.

Ìjọba Naijiria fèsì sí òfin tí UK fi dèé nítorí ẹ̀dà Covid-19, Omicron

Awon arinrinajo

Oríṣun àwòrán, Reuters

Minisita eto ilera ni Naijiria, Dokita Osagie Ehanire ti sọ pe ko bojumu bi ijọba orilẹ-ede United Kingdom ṣe kọ orukọ Naijiria mọ awọn orilẹ-ede to fofin de nitori ẹda aarun Covid-19 Omicron.

Ehanire sọ pe "inu wa ko dun nigba ti wọn fi orukọ orilẹ-ede mẹfa ni Africa si ara awọn ti ko le wọ ilẹ UK."

O ni ko tii si imọ pupọ nipa ẹda Omicron, ati pe orisirisi ọna ni amojuto fi wa fun aarun Covid-19.

Ọjọ Aiku ni Ehanire ti sọ ọrọ naa lori eto kan lori amohunmaworan Channels TV.

Eyi waye lẹyin ọjọ kan ti ijọba UK fi ikede naa sita.

Dokita Ehanire sọ pe nkan to daju ni pe ẹda tuntun naa ko tii seku pa ẹnikẹni tabi se aisan kọja bo se yẹ.

O ni igbesẹ fifi ofin de awọn orilẹ-ede ti yá ju, ti yoo si ni ipa ti ko dara lara eto ọrọ aje, to fi mọ igbokegbogo lasiko ọdun Keresimesi ati ọdun tuntun.

OSAGIE EHANIRE

Oríṣun àwòrán, OSAGIE EHANIRE

Àkọlé àwòrán, Minisita eto ilera ni Naijiria, Osagie Ehanire

Bakan naa lo sọ pe lootọ ni awọn ri aarun Covid-19 lara awọn arinrinajo lati UK, o ni ṣugbọn ko si aridaju pe ẹda Omicron ni.

"Fifi ofin de awọn orilẹ-ede lati ma wọ ilẹ United Kingdom ko le ṣe anfaani kankan fun igbogunti aarun Covid-19.

"Awa gẹgẹ bi orilẹ-ede Naijiria ko ri fifi ofin de irinajo baalu ati awọn eeyan ni anfaani kankan."

Orilẹ-ede Canada ati America lo kọkọ kede ofin to de awọn arinrinajo lati awọn orilẹ-ede kan nilẹ Africa nitori ẹda aarun Covid-19, Omicron.

Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ̀sì ti fi Nàìjíríà si àra àwọn orílẹ̀dè tí kò le wọ orílẹ̀-èdè wọn nítori ẹ̀ya Covid-19 Omicron

Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, yóò máa bèrè fún àyẹ̀wò covid-19 lọ́wọ́ arìnrìnàjò kankan to bá fẹ́ wọ orílẹ̀-ède wọn pàápàá jùlọ láti Nàìjíríà.

Bákan náà ni arìnrin àjò kọ̀ọ̀kàn yóò ní láti wà ni ìgbélé fún ìgbà díẹ̀ tí wan bá wọ ilú lójíunà láti mú àdínkù bá ìtànkálẹ̀ ààrùn ẹ̀yà Covid-19 Omicron.

Mínísítà ètò ilèra Sajid Javid sọ èyí lónìí ọja Abamẹta, pé èyí ṣe pàtàkì láti ri dájú pé ààrùn náà ko tàn kálẹ̀ , nígbà ti àwọn onímọ̀ sáyẹ̀nsì ń gbìyànjú láti mọ̀ si nípà ẹ̀yà náà.

Pàápàá jùlọ bí o ṣe ń ran àti bi abẹ́rẹ́ àjẹsára covid ṣe lágbára sí lórí rẹ̀.

Javid ni láti bi ọ̀sẹ̀ kan ti ìròyin ààrùn náa tí n tàn ka ni àwọn ti ri ìwòye pé o ń tànkálẹ̀ nítori ìrìnajò ni.

Asojú ìjọba ill Gẹ̀ẹ́sì Boris Johnson pe fífi òfin de àwọn orílẹ̀-èdè yìí ja ọ̀nà áti dpenà ìtànkálẹ̀ rẹ̀.

Àkọlé fídíò, Teslim Thunder Balogun: Àwọn oní-Tomato, aláta, oníṣu á máa kó ọjà wọn lọ́fẹ̀ẹ́ sínú ọkọ̀

" Sáájú náà ni a ti sọ pé kò ni fi ohunkóhun falẹ̀ ni àsìkò tí o bá yẹ, ti bí nnkan se ri ba gba pé ki a fi ofin de àwọn ènìyàn , o ti pọ́n dandan bẹ́ẹ̀ náà ni a ó ṣe ṣee.

Láti àsìkò yìí lọ gbogbo ẹni ti o ba pọndandan fún láti wọn UK, yóò se àyẹ̀wò arun Covid-19 ni ọja meéjì si àsìkò tí yóò wọ bàálú

Àkọlé fídíò, Ṣé lọ́òtọ́ ọkọ àti ìyàwọ́ ní Mr & Mrs Kogberegbe? Àṣírí bí a ṣe ń ṣe ètò yìí rèé...

Ní báyìí wọn ti gbé àlàpupa lé orí orúkọ Nàìjíríà , èyí túmọ̀ sí pé àra àwọn orílèedè ti o léwu fún ààrùn Covid-19

Javid ṣàlàyé pé, iye àwọn ti o ti ni ààrùn Covid-19 Omicron ni ilẹ̀ Gẹ̀ẹ̀sì ń ps si lójòòjúmọ́ ti o si ti tó ènìyàn ọgọ́jọ báyìí, ti o si jẹ pé àwọn to rin irin àjò lọsi orilede Nàìjíría lo tun gbe ìgbá orókè lẹ́yìn South Africa.

Àkọlé fídíò, Davido yàtọ̀ s'àwọn ọ̀dọ́ olórin kan tó lè yẹ̀yẹ́ àgbà olórin, òun ló kọ́kọ́ ná mi ní béèlì N1M lágbo - Yinka Ayefele

South Africa àti àwọn orílẹ̀ mẹ́sàn mííràn láti ìhà gúúsù Africa ni wọn tun fi sibẹ ni opin ọsl to kọja. Itumọ̀ èyí si ni pé, àwọn ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nìkan tàbi àwọn to ni ìwé ìgbélùú nìkàn ni o ni àànfàni láti wọlé, wọn yóò sì ni láti wa ni ìgbélé ni ile ìtura fún ìgbà díẹ̀.

Àkọlé fídíò, Àwọn òṣìṣẹ́ Adedoyin jẹ́wọ́ fún wa pé àwọn pa àbúrò mi, ọ̀gá Adedoyin sì mọ̀ síi - Ẹ̀gbọ́n Timothy Adegoke

Àwọn orílèdè tí UK fi òfin de

South Africa

Botswana

Eswatini

Lesotho

Namibia

Zimbabwe

Angola

Mozambique

Nigeria

Zambia