Coronavirus Vaccine: Ẹ̀ wo bàbá àgbàlagbà tó lo ayédèrú apá nitorí kò fẹ́ gba abẹrẹ́ àjẹsára Covid-19

Coronavirus

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ọwọ ti tẹ arakunrin kan lorilẹede Italy to lo ayederu apa ko le e gba sabukẹ pe o ti gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19.

Oṣiṣẹ ijọba to fi ọrọ naa lede ni nọọsi to fẹ fun baba ẹni aadọta ọdun naa ni abẹrẹ ajẹsara naa lo ri pe ayederu apa ni o lo, ni ireti pe ko si ẹni ti yoo mọ

Amọ nọọsi naa to ri pe apa naa ko ri bo ṣe yẹ ni apa ''silicone'' lo fi bo oju apa rẹ, ti o si fi ẹjọ baba naa sun awọn ọlọpaa.

Nọọsi naa ni lasiko ti oun ṣi apa ọkunrin naa lati fun ni abẹrẹ ajẹsara naa ni o ri pe ko si ẹmi ni ọwọ naa , to si dabi rọba to tutu, ti isan rẹ ko tun yọ bo ṣe to.

Lẹyin ti aṣiri baba naa tu ni o sọ fun nọọsi naa ko gbagbe nkan ti o ri, amọ nọọsi naa fi ẹjọ rẹ sun fun iwa ayederu.

Ileeṣẹ ọlọpaa wa fikun un pe awọn ti bẹrẹ iwadii iṣẹlẹ naa ni agbegbe Biella, ni Italy.

Coronavirus

''Ohun to ba wa ninu jẹ ni pe ọpọlọpọ eniyan ni ẹmi rẹ ti ṣọnu lori iṣẹlẹ ajakalẹ arun Coronavirus ni orilẹede naa, nitori naa ko yẹ ki ẹnikẹni hu iwa ti baba naa hu nipa lilo ayederu apa.''

''Ki n se ohun to bojumu ni baba yii ṣe pẹlu iye eniyan ti aarun naa ti mu ẹmi wọn lọ to fi mọ ọrọ aje to ti dẹnukọlẹ.''

Bakan naa ni iroyin fikun un pe oṣiṣẹ eto ilera ni baba agbalagba naa, ti wọn si ti le kuro lẹnu iṣẹ nitori ko tii gba abẹrẹ ajẹsara, to si pọn dandan fun awọn oṣiṣẹ eto ilera ni Italy.

Eleyii ko ṣẹyin igbesẹ ijọba orilẹede Italy lati ri pe o pọn dandan fun awọn eniyan lati gba abẹrẹ ajẹsara naa fun idẹkun itankalẹ aarun Covid-19.