Dowen college student death: Ohun tí ọmọ mi, Sylvester Oromoni sọ fún wa nì yìí nínú ìrọra kí ó tó kú

Oríṣun àwòrán, others
Baba to bi akẹkọọ ile ẹkọ Dowen College,Sylvester Onoromi ti wọn ni awọn akẹgbẹ rẹ kan lu pa nitori pe ko dara pọ mọ ẹgbẹ okunkun, ti fesi lori ọrọ ti ile ẹkọ naa sọ pe o farapa nigba to n gba bọọlu ni.
Alagba Slvester Onoromi sọ ninu ifọrọwerọ pẹlu ileeṣẹ BBC Pidgin pe Oromoni sọ fun oun pe oun ko gba bọọlu tabi farapa bi ile ẹkọ naa ṣe sọ.
Baba Sylvester ni ọmọ oun Junior bi o ṣe ma n pe sọ fun oun pe oun ko gba bọọlu kankan bi ileewe naa ṣe sọ.
- Ibi tí ọ̀rọ̀ dé dúró rèé lórí ikú akẹ́kọ̀ọ́ Sylvester Oromoni tí wọ́n ní àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn ní Dowen College lù pa
- Ṣé lóòtọ́ ni ajínigbé sọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ méjí di iṣu ní Ibadan?
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ àwọn òbí ọmọ ọdún 15 tó yìnbọn pa èèyàn mẹ́rin nílé ẹ̀kọ́
- Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ondo sọ̀rọ̀ lórí ìdájọ́ tó dá Sotitobire láre pé kò jí ọmọ kankan gbé
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá kéde ìgbaniṣíṣẹ́ fáwọn àkàndá ẹ̀dá
- Àwọn ọ̀dọ́ Eruwa ṣe ìwọ́de lórí ikú Timothy Adegoke tó kú sílé ìtura ní Ife
Ọmọ naa ni awọn akẹkọkunrin marun un lo wọ yara awọn, ti wọn pa ina ti wọn si bẹrẹ si ni na oun niwaju awọn akẹkọọ to ku, ki wn to salọ.
Baba Sylvester ni kii ṣe igba akọkọ ni yii ti wọn yoo fi iya jẹ ọmọ naa ni ileẹkọ oun ti awọn si ti fi ẹjọ sun awọn alaṣẹ ileẹkọ naa.
Bi ọmọ mi ṣe ku re e...
''Ọjọ Kọkanlelogun, Osu Kọkanla ni ileẹkọ naa pe iyawo mi pe ọmọ wa ni ileewosan ileẹkọ naa lẹyin to farapa.''
''Ọmọ mi agba to n lọ si London ni ọjọ keji ni mo ni ko lọ si ileẹkọ rẹ ni Eko ko lo wo ọmọ naa.''
''Nigba ti o de ibẹ lo ni oun ko gbagbọ pe bọọlu ni ọmọ naa gba to fi ri bi oun ṣe ri''

''O ni ẹyin ọmọ naa ti tẹ ti ko si le e dide nitori ẹyin rẹ wu pẹlu apa kan ikun rẹ.''
''Ẹnu rẹ dudu ti wọn si gbe lọ si ile ni Eko amọ ko le e sun, ti ọmọ mi agba to lọ wo o ni ileẹkọ ni ko ṣeeṣe ki eleyii jẹ erebọọlu lo fa irọra ti ọmọ naa wa.''
''Wọn ṣe ayẹwo ẹjẹ ati ara fun to fi mọ ti aisan iba , to si bẹrẹ si ni gba oogun, amọ ẹnu rẹ bẹrẹ si ni bo lẹyin to bẹrẹ oogun naa.''
Ọjọ Kọkandinlọgbọn ni ọmọ naa jẹwọ fun iya rẹ pe'' mummy, mi o subu, mi o gba bọọlu, awọn wọnyii wọle wọn si bẹrẹ si ni na mi ti awọn akẹkọọ to ku si sa jade.''
''Wn dunkoko mọ wọn lati pa wọn ti ẹnikẹni ba jẹwọ ninu wọn.''
Baba Sylvester ni ẹya ara ọmọ naa bẹrẹ si ni wu paapaa ẹdọ rẹ nitori ẹjọ ko san ni ara rẹ, ati pe ọmọ naa gbe ẹmi mi ki oun to gbe e lọ si ilewosan ẹkọni Teaching Hospital ni ilu Warri.
Bakan naa ni baba rẹ ni ọmọ naa fi to wọn leti pe wọn fun oun ni nkan mu to dabi ''chemical''.
Ohun ti ile ẹkọ Dowen sọ ni pe Oromoni farapa nigba to n gba bọọlu nitori naa lawọn fi ni ki awọn obi rẹ gbe lọ sile.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Bí mo ṣe dáná sun àlè ọkọ mi tí mo tún fẹ́ sá lọ nípinlẹ̀ Ogun - Ìyàwó ilé
- Wo àwọn ìdí tí Adájọ́ fi dá Wòlìí Sotitobire láre, tó sì da ẹ̀wọ̀n gbére nù
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá kéde ìgbaniṣíṣẹ́ fáwọn àkàndá ẹ̀dá
- Ìjọ Redeem gbé ojú òpó olólùfẹ́ kalẹ̀ sórí ayélujára fáwọn ọ̀dọ́ láti pàdé ọkọ tàbí aya
- Òfo ni 'White Paper' Sanwo-Olu kò sí ǹkan tó n jẹ́ bẹ́ẹ̀ lábẹ́ òfin - Adegboruwa
- Àwọn ọ̀dọ́ Eruwa ṣe ìwọ́de lórí ikú Timothy Adegoke tó kú sílé ìtura ní Ife
- Wo orílẹ̀èdè tí ẹ̀dà Covid-19 tuntun Omicron rápálá wọ̀ l‘Áfíríkà
- Èsì iléẹ̀kọ́ Dowen rèé sí ìkú akẹ́kọ̀ọ́ tí àwọn òbí rẹ̀ ní àwọn ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn pa nítorí kò darapọ̀ mọ́ wọn!
Baba ọmọ naa sọ pe ọmọ rẹ ni awọn ọmọkunrin marun un kan lo wọ inu iyara rẹ, ti wọn si bẹ́rẹ si ni lu nitori pe ko bawọn ṣe ẹgbẹ okunkun.
Arakunrin Sylvester Onoromi Snr ni eleyi kii ṣe igba akọkọ ti wọn yoo dẹyẹ si ọmọ oun ati pe awọn ti fẹjọ sun alaṣẹ ile ẹkọ naa lọpọ igba.

Oríṣun àwòrán, The Cable
Iroyin iku Sylvester lu sita laipẹ yi nigba ti eeyan kan,Perrison Oromoni, kọ nipa rẹ soju opo Twitter pe ile ẹkọ Dowen n parọ pe awọn ẹgbẹ okunkun kọ lo lu ibatan oun to si ṣokunfa iku rẹ.
Ko pẹ si igba yi ni Sylvester ku si ile iwosan ti wọn ti n tọju rẹ.
Ijọba Eko ti ileẹkọ Dowen pa:
Atẹjade kan ti Kọmisana feto ẹkọ nipinlẹ Eko, Folasade Adefisayo fisita lọjọ Ẹti lo sisọ loju ọrọ yii.
Atẹjade naa salaye pe isẹlẹ yii pọn dandan ki iwadii ijọba lori isẹlẹ naa le fẹsẹmulẹ, lati mọ orisun iku to pa akẹkọọ naa lai pe ọjọ.

Èsì iléẹ̀kọ́ Dowen rèé sí ìkú akẹ́kọ̀ọ́ tí àwọn òbí rẹ̀ ní àwọn ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn pa nítorí kò darapọ̀ mọ́ wọn

Oríṣun àwòrán, Others
Agbẹnusọ ile ẹkọ Dowen, Ayomide Falona ni ko si otitọ ninu iroyin to sọ pe awọn akẹkọọ kan ni ile iwe naa lo lu Sylvester pa.
Ọgbẹni Falona ni iṣẹ iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa.
Ninu atẹjade ti ileewe Dowen fi sita ni wọn ti sọ wi pe awọn olutọju awọn akẹkọọ to n gbe ninu ileẹkọ naa lo kọkọ so fun awọn alaṣẹ ileẹkọ naa pe ni Ọjọ Kkanlelogun, Osu Kọkanla ni akẹkọọ naa farapa lasiko to n gba bọọlu pẹlu awọn akẹgbẹ rẹ.
- “Màá ṣúgbàá gbígba ₦25m ẹ̀tọ́ Baba Suwe lọ́dọ̀ NDLEA lẹ́yìn ikú rẹ̀”
- N kò fara mọ́ ẹ̀rí Princess, ẹ yọ́ dànú torí kò bá òfin mu - Baba Ijesha yarí nílé ẹjọ́
- Òṣìṣẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ ló sin Timothy Adegoke, akẹ́kọ̀ọ́ OAU tó kú sílé ìtura - Agbẹjọ́rò
- "Ajínigbé, ẹ sá kúrò nílẹ̀ Yorùbá, àwa Agbekoya ti jáde"
- Abubakar Malami kéde àwọn agbébọn bíi agbésùnmọ̀mí lẹ́yìn ò rẹyìn
Lẹyin naa ni nọọsi ileewe naa fun ni itọju akọkọọ, to si pada si yara rẹ.
Wọn ni ni ọjọ keji ni o bẹrẹ si ni sọ wi pe ibadi n rọ ohun, ti dokita si sayẹwo rẹ ki wọn to pe iya rẹ ko wa gbe lo fun ayẹwo inu ara.
Bakan naa ni wọn ni iya rẹ pe ileẹkọ pe ayẹwo rẹ ko fihan pe o ni egbon kankan ninu ara tabi ẹya ara rẹ kankan ṣẹ.

Oríṣun àwòrán, Perrrie
Nitori naa wọn ni irọ balau ni iroyin to n sa ranyin naa pe ki akẹkọọ to ku, o darukọ awọn akẹgbẹ rẹ to fẹsun kan pe wọn ni ki oun wa darapọ mọ ẹgbẹ okunkun.
''O yawa lẹnu nitori a ti fi ọrọ wa awọn akẹkọọ yii lẹnu, ti o si fihan pe ko si otitọ kankan ninu iroyin naa''
''Bakan naa ni ko ba ẹnikẹni ja lasiko naa, ti ko si si ẹni to dunkoko mọ ọ ninu ileẹkọ naa''
Ileẹkọ Dowen ni iya rẹ ko tete wa mu u, ko to ran ẹlomiran lati wa fun ni ileẹkọ naa fun ayẹwo
Bakan naa ni alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Adekunle Ajisebutu ni oun ko tii gbọ nípa ìṣẹlẹ naa.
Ṣé lóòótọ́ ni akẹ́kọ̀ọ́ girama ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn pa akẹ́kọ̀ọ́ míì l'Eko?
Iku akẹkọọ ile ẹkọ Dowen College niluu Eko, Sylvester Oromoni jẹ iyanlẹnu fun ọpọ eeyan.
Ohun ti a gbọ ni pe awọn akẹkọọ akẹgbẹ Oromoni to jẹ ẹlẹgbẹ okunkun ni wọn lu laluki nitori pe o kọ lati darapọ mọ ẹgbẹ okunkun pẹlu wọn.
Iroyin sọ pe Oromoni darukọ awọn to lu u ki ẹmi to bọ lẹnu rẹ nile iwosan.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- 'Oṣù mẹ́sàn-án ni wọ́n fi jí mi gbé tí wọ́n ń fipá bá mi lòpọ̀ títí tó fi di oyún'
- Ó tó gẹ́ẹ́, ẹ fi Sunday Igboho sílẹ̀, Agbekoya yarí
- 'Gbogbo ọlọ́pàá tó ń gbégidínà lọ́nà àìtọ́, ẹ yọ wọ́n kúrò'
- Mo fún òṣìṣẹ́ tó bá fẹ́ du ipò gómìnà di December 18 láti fi ipò tó wà sílẹ̀ - Gómìnà Fayemi
- Bí àdúrà ọjọ́ kẹjọ àti ayẹyẹ òkú Baba Suwe yóò ṣe lọ rèé
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí méje tó ń pa èèyàn ṣe ètùtù ọlà l‘Ogun
- Obìnrin ẹni ọdún 28 kú lọ́jọ́ ìgbéyàwó rẹ̀, ariwo sọ!
Ọjọ Ẹti ọsẹ to lọ ni wọn gbe Oromoni lọ si ile iwosan niluu Eko, amọ ọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii lo ku.
Ẹbi ọmọ naa, Perrison Oromoni lo ṣalaye bi ọdọmọde akẹkọọ ṣe ku loju opo ikansiraẹni Twitter rẹ.
O ni ọmọdekunrin naa gbẹmi mi lẹyin ti ayẹwo X-ray at'awọn ayẹwo mii fihan pe o ti ṣeṣe ni inu ara lẹyin ti awọn akẹẹgbẹ rẹ ẹlẹgbẹ okunkun lu u.
O ni niṣe ni gbogbo ara rẹ wu, ki o to faye silẹ lọjọ Ìṣẹgun.
"Ki Sylvester to ku ni wọn ti sọ fun un pe ki o darapọ mọ awọn, a ti pe ko gbọdọ sọ fun ẹnikan bi bẹẹ kọ, iku ni yoo gbẹyin rẹ.
Perrison ni Sylvester lo darukọ awọn akẹgbẹ rẹ ti wọn ni ko darapọ mọ ẹgbẹ awọn ki o to ku.
Ile ẹkọ Dowen pe ẹgbọn baba mi lati sọ fún un pe Sylvester ṣeṣe nigba ti o n gba bọọlu lọgba ile ẹkọ naa ni.
Amọ, Sylvester ni awọn akẹgbẹ oun lo lu oun lalubami."

Oríṣun àwòrán, Perrie
Mọlẹbi fi fidio sita to safihan Slyvester to n pọ ẹjẹ lẹnu ki o to gbẹmi mi
Perrison wa sọ loju opo ayelujara rẹ pe ohun to ba gba, l'awọn yoo fun ọrọ naa, o ni Sylvester ko ni ku lasan.
O ni awọn orukọ to da ki o to ku ni Anslem Temile, Michael Kashamu ati Benjamin Favour.
Bakan naa ni o fi fidio lede nibi ti ọmọ naa ti n jẹrora iku, ti ẹjẹ si n jade ni ẹnu rẹ pẹlu ete rẹ to n ṣejẹ.
Awọn obi rẹ ko le e fi mọra ti wọn si n fi epe ranṣẹ si awọn akẹkọọ ti wọn ṣe ọmọ wọn basubasu.
Lẹyin naa ni a ri aworan ọmọ to ti gbẹmi mi.



















