Baba Suwe: Bí àdúrà ọjọ́ kẹjọ àti ayẹyẹ òkú Baba Suwe yóò ṣe lọ rèé

Aworan ikede oku Baba Suwe

Ipalẹmọ fun eto adura ọjọ Kẹjọ ati ayẹyẹ oku adẹrinposonu nii, Babatunde Omidina, ti ọpọ eeyan mọ si Baba Suwe ti debi to ni apẹrẹ bayii.

Bẹẹ ba gbagbe, Baba Suwe lo jade laye ni ọjọ Aje, ọjọ Kejilelogun osu Kọkanla ọdun 2021, ti wọn si sin oku rẹ ni Ọjọbọ, ọjọ Kẹẹdọgbọn osu Kọkanla bakan naa.

Baba Suwe naa lo dagbere faye lasiko aisan ọlọjọ pipẹ lẹni ọdun mẹtalelọgọta.

Atẹjade kan ti ọmọ oloogbe, Adesola Omidina fisita loju opo Instagram rẹ salaye pe Ọjọbọ ọla ni wọn yoo se ayẹyẹ isinku ati adura ọjọ mẹjọ fun oloogbe naa.

Ile rẹ to wa ni agboole Baale, adugbo Ewu-Elepe ni Ijede nilu Ikorodu ni eto adura ati ayẹyẹ oku naa yoo ti waye.

Atẹjade naa fikun pe deede aago mọkanla aarọ ni eto adura fun oloogbe naa yoo bẹrẹ, ti awẹjẹwẹmu oku yoo si tẹle.

Àkọlé fídíò, Gbọ́ ohun ti àwọn òṣèré tíátà Yoruba sọ fún BBVC nípa Baba Suwe

Ireti wa pe ọpọ awọn eeyan jankan jankan lagbo ere tiata ni yoo peju sibi adura ati ayẹyẹ ijade oku naa.

Bi awọn eto naa ba si se n waye, ni BBC Yoruba yoo maa mu wa fun igbadun yin.

A si n gbadura pe ki Ọba Oke tẹ Baba Suwe si afẹfẹ rere.