Baba Suwe: Àwọn ǹkan tí ọ̀pọ̀ kò mọ̀ nípa Baba Suwe

Baba Suwe

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán, Baba Suwe: Àwọn ǹkan ti ọ̀pọ̀ ko mọ nípa Baba Suwe
    • Author, Yemisi Oyedepo
    • Role, Broadcast Journalist

Ilẹ̀ to mọ lówùrọ̀ òní, ọ̀rọ̀ àwọn adẹrinpòsónu eléré tíàtà Yorùbá lo gba orí ayélujára kan.

Ohun tó sì fa àríyànjiyan náà ni pé, ibeere ru soke pe taa ni o lé panilẹ́rin jù nínú Babatunde Omidina ti gbogbo ènìyàn mọ si Baba Suwe àti Bolaji Amusan ti gbogbo ènìyàn mọ si Baba Latin.

Ẹ̀wẹ̀ nínú àriyanjiyan náà ni ọ̀pọ̀ ti fi idí rẹ̀ múlẹ̀ pé Baba Suwe lo ti wa láye láti ìgbà ti ẹfẹ ninu eré tíata ti bẹ̀rẹ̀.

Tani Babtunde Omidina?

A bí Babatunde Omidina ( Baba Suwe)ni inú oṣù kẹjọ ọdun 1958 ni opopona Inabere to w ni Lagos Island sùgban ọmọ Ikorodu ni ìpíinlẹ̀ Eko ni.

O lọ ilé iwé alakọbẹrẹ Islamia ni ipinlẹ Eko àti Osogbo ki o to lọ si ilé ẸKỌ Adekanbi Commercial High School, ni agbegbe Mile12 ni ìlú Eko sùgbọ́n ilú Osogbo lo ti gba iwé ẹri WAEC.

O bẹ̀rẹ̀ èré ori itage ni ọdun 1971 ṣùgbọ́n nínú agbélewò Omolasan ni ìràwọ rẹ ti tàn sita, bakna naa lo tun tàn sii lẹ́yin to fara han ninu eré Iru Esin eyi ti Olaiya Igwe gbé jáde lọ́dun 1997.

O ti ṣe oniruuru ere tiata pẹ̀lú àwọn òṣeré jankanjankan to fi mọ funke Akindele atI Adebayo Salami.

Lọdun 2011 ìròyìn tàn ká pe Baba Suwe gbé òògun oloro sùgbọ́n ti o ni kò si òòtọ kankan nínú ọ̀rọ̀ náà to si pada gbé ajọ to n gbogun ti òògun oloro lọ́rilẹ̀-èdè Naijiria NDLEA lọ si ilé Ejọ

Ilé Ẹjọ pada dájọ pe ki wọ́n san mílíọnu marundinlọ́gbọ̀n gẹ́gẹ́ bi owo ìtànran , sùgbọ́n ti Baba Suwe salaye pe àjọ NDLEA kọ lati ṣe ǹkan ti ilé ẹjọ sọ

Baba Suwe ti kopa nínú ere ọlọsọọsẹ ni LTV 8 ati Erin Keke ni NTA Channel 7 nípinlẹ̀ Eko

Orúkọ ọrẹ́binrin Baba Suwe ni wọ́n fi n pèé ni Baba Suwe

Bab Suwe ni oun ti ṣe fiimu to lé ni ogojibayii.