Osun Accident: Àwọn ọmọ ijọ wa tí fí ìgbàgbọ́ gbà ìṣẹlẹ ìjàmbá ọkọ́ - ìjọ Kátólíkì

Aworan ijamba ọkọ

Iroyin ti bẹrẹ si ni suyọ diẹ diẹ nipa bi ijamba ọkọ to mu eeyan meje lọ ṣe ṣẹlẹ ni ipinlẹ Oṣun.

Alakoso ẹka eto nile iwosan Lady of Fatimah Catholic Hospital Rev Fr Femi Oloyetombi lo na ọrọ naa nibẹ fun ileeṣẹ BBC YORUBA.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo, o sọ pe obinrin kan to sọda titi mọ ọkọ lẹnu lo ṣokunfa ijamba naa.

Oloyetombi ni ọna ti ọkọ ọhun gba loun gan naa gba kọja tori oun naa lọ fun ipagọ adura.

O fi kun ọrọ rẹ pe ti a ba fi obinrin naa kun awọn mẹfa to ku ninu ọkọ naa, iye ẹmi to ba iṣẹlẹ naa lọ yoo jẹ meje.

O ni kete ti wọn pe oun lori ẹrọ ibanisọrọ toun si pe awọn akẹgbẹ oun nile iwosan lawọn tete fọwọ kun awọn ajọ ẹṣọ oju popo lati maa ko awọn to ku ati awọn to fara pa lọ si ile iwosan.

Oloyetombi ṣalaye pe ko si akoko lati maa bere ẹjọ pe ki lo ṣẹlẹ lasiko ati doola ẹmi ṣugbọn "oun ti mo gbọ ni pe igbiyanju dẹrẹba ọkọ lati yago fun obinrin to fẹ sọda titi ni ko ri ọwọ ara rẹ dari".

Femi Oloyetombi tubọ ṣalaye pe awọn ọmọ ijọ katoliki ti iṣẹlẹ naa kan lawọn ti fi igbagbọ gba iṣẹlẹ ọhun tawọn si gbadura pe ki Ọlọrun dawọ le awọn to n gba iwosan ati pe ko fun awọn ti lọ ni isinmi rere.

''Ijọ ti kan si awọn mọlẹbi ti ọrọ yi kan kaakiri lati tu wọn ninu. Gẹgẹ bi ẹlẹran ara, ọrọ yii dun wa ṣugbọn ko si nkan ti a fẹ ba Ọlọrun fa''

Awọn olujọsin ti o fara kasa iṣẹlẹ yii n mbọ lati ipade adura to waye ni Oke Maria ni agbegbe Lagere, Ile Ife.

Ipade yii jẹ ipade adura apapọ ijọ Katoliki to maa n waye lọdọọdun.

Àkọlé fídíò, Ọja Arena Oshodi ni àwọn èèyàn ti ń r'aja