State of Osun:Pípe ìpínlẹ̀ Osun ni State of State Osun kò bá òfin mu-Adájọ́ Agboola
Adájọ ilé ẹjọ́ gíga kan ní ìpińlẹ̀ Osun tí dájọ́ pé, pípe ìpínlẹ̀ Osun ní State of Osun kò bá ofin mú.
Ìdájọ́ náà wáyé lẹ́yìn ti ajàfẹ́tọ ọmọnìyàn kan tó tún jẹ́ agbẹjọ́rò Kanmi Ajibola gbé ìjọba ìpińlẹ̀ Osun lọ silé ẹjọ́ nítori owó ori mílíọ̀nù meje lé díẹ̀ ti wọ́n fún pé kó san, tó sì ni owó náà kò bójú mu tó fún irú iṣẹ́ tí òun ṣe gẹ́gẹ́ bi ajàfẹ́tọ́ ọmọnìyàn
Agbẹjọ́rò ọ̀hún kanmi Ajibola lásìkò to n bá BBC Yorùbá sọ̀rọ̀ sàlàyé pé, ọgbẹ́ni Raufu Aregbẹsọla ní òun gbé lọ sílé ẹjọ́ láti ǹkan bii ọdun mẹ́tà sẹyin nítori àwọn àyipada tó ṣe ni ìpínlẹ̀ Osun ti kò sì bá òfin mu àti pé nítoripé àkọle tó wà lórí àwọn lẹ́tà tí wọ́n fi bèrè owó orí náà (Government of the State of Osun)ti ko bá òfin Naijiria mu.

Oríṣun àwòrán, others
Ajibola ni owó orí náà ko bojú mú tó bótilẹ̀ jẹ́ pe ilé ìgbìmọ̀ asofin ló gbé ofin náà kalẹ̀, adájọ gba eyí ó sì pàṣẹ pé ofin náà kò tọ̀nà bí Ajibola ṣe sọ.
Ajàfẹ́tọ ọmọnìyàn náà ní pé inú òun dùn gidigidi lóri ìdájọ ilé ẹjọ́, èyí yóò sì tún ràn àwọn ará ilú míràn lọ́wọ́ lóri lati le jà fún ẹ̀tọ́ wọ́n ti ìjọba bá ṣe oun ti kò tọ́.
Ẹ̀wẹ̀ adájọ ní orúkọ tí ìjọba ìpínlẹ̀ Osun ń pe ìpińlẹ̀ náà kò bá òfin orílẹ̀-èdè Nàìjíríà mu.
BBC News Yoruba pé kọmísọnà fún ìbánisọ̀rọ̀ nípinlẹ̀ Osun Funke Egbemode láti sọ èrò ọkàn ìjọba lóri ìdájọ ilé ẹjọ́ náà sùgbọ́n o ní ìjọba kò ni ǹkankan láti sọ lórí ìdájọ́ ọ̀hún báyìí.
" A kò tíi'ni ìdáhùn kankan sí ọ̀rọ̀ yìí báyìí, tí a ba ti ní ǹkan sọ, à ó pè yín."
Yàtọ̀ f'àwọn mẹ́fà tó n bọ̀ láti ìpàgọ̀ àdúrà tó kú, àjọ FRSC Osun sọ ipò táwọn tó fara pa wà báyìí
Osun Accident: Ọgbọ̀n ọjọ́ ni a tó leè sọ pàtó ìròyìn míì fún aráàlú

Oríṣun àwòrán, OTHER
Alabojuto ẹkun fun ajọ awọn ẹṣọ ojú popo ni agbegbe ti ijamba ọkọ to n gbe awọn to m bọ lati ipagọ adura ti ṣẹlẹ sọ fun wa ipo ti awọn to ku wa.
Ọgbẹni Ọkẹ Peter ni kete ti wọn pe ileeṣẹ awn naa lawọn ti de ibẹ ti awọn si ri i pe eeyan mẹfa ku ti mẹrinla si fara pa.
Awọn olujọsin naa m bọ lati Oke Maria ti ijọ ti wọn si wa ni agbegbe Lagere, Ile Ife. Ipade yii jẹ ipade adura apapọ ijọ Katoliki to maa n waye lọdọọdun bẹẹ si ni awọn to wa eleyii le ni ẹgbẹrun.
O jẹ ko di mimọ pe nigba ti awọn ṣebẹwo si ile iwosan ti wọn ko gbogbo wọn lọ naa ni awọn ti ri aridaju pe eeyan mẹfa lo ba iṣẹlẹ naa rin.
- Èèyàn mẹ́fá tó m bọ̀ láti ìpàgọ́ àdúrà kú nínú ìjàmbá ọkọ̀ ojú pópó l'Osun
- Ohun tí a mọ̀ nípa ààrùn tó ń pani ní Nàìjíríà tí kìí ṣe CoronaVirus, Lassa, tàbí Ebola rèé
- Èèyàn mẹ́rin tún di olóògbé lẹ́yìn tí wọ́n lùgbàdì Ibà Lassa
- Ṣọ̀ra! Ò leè kó sí pańpẹ́ ọlọ́pàá bí o bá na ọmọ rẹ - Ajàfẹ́tọ̀ ọmọdé
- BBC tún gbé e dé! Wọ́n tú àṣírí ìfiyàjẹni àwọn Ológun àti SARS káàkiri Nàìjíríà
Ẹwẹ ni ibamu pẹlu ilana awọn ẹṣọ oju popo, alabojuto ẹkun ọhun sọ pe yoo to ọgbọn ọjọ ti awọn yoo fi wo iṣẹlẹ ọhun, awọn to tun fara pa tabi iṣẹlẹ mii to rọ mọ ọ.
Ọgbẹni Ọkẹ lo sọ fun BBC pe gẹgẹ bi awọn ṣe gbọ, dẹrẹba to wa ọkọ ọhun toun naa n sa ere ju bo ṣe yẹ lọ tori ọna yẹn jẹ ọna ti ko da to ni ọpọlọpọ kọrọkọrọ.
"Nigba ti ọrun ọkọ naa yiwọ ti dẹrẹba du u titi ti ko ri i du, o yi sinu koto".
Ọkẹ ni tori o jẹ ipejọpọ awọn to n lọ si ijọ kan naa, wọn mọ ara wọn nitori naa gbogbo ẹbi awọn to gbẹmi mi ati awọn to fara pa ti mọ si i ti wọn si ti yọju.













