Ọ̀pọ̀ ẹ̀mí sọnù sínú ìjàmbá iná l'órílẹ̀èdè Ghana

Ibudo ijamba ọkọ naa

Oríṣun àwòrán, TV3 GHANA

Ogunlọgọ eniyan lo ti padanu ẹmi wọn lẹyin ti ọkọ bọọsi meji kọlura wọn laarin gbungbun Ghana.

Botilẹjẹ wi pe iye awọn to ku ko ti i fojuhan bayii, oṣiṣẹ ijọba kan sọ fun BBC pe o le ni aadọta eniyan to ti ku, ti ọpọlọpọ si farapa.

Awọn ọlọpaa ati oṣiṣẹ pana-pana ti wa ni ibi ti ijamba naa ti waye.

Ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe ni nkan bi aago meji oru ni ijamba naa waye ni agbegbe Kintampo South.

Iroyin sọ pe ẹmi to sọnu pọsi nigbati ọkan lara awọ̀n ọkọ naa gbina lyin ti wn kọlu ara wọn.

Àkọlé fídíò, Manfe-Dove: Àgbà ìlú kan ní ohùn kan ló fọ̀ sáwọn baba ńlá àwọn láti ṣe bẹ́ẹ̀