Collapsed Building: Ilé alájà mẹ́rin wó l'Eko
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post
Iye eeyan to ti jẹ Ọlọhun ni pe ninu ijamba ile to wo ni ipinlẹ Eko ti di ogun bayii, eyi jẹ ohun ti ijọba ipinlẹ̀ Ẹko sọ.
Kọmisana fun eto ilera ni ipinlẹ naa Jide Idris lo fi idi ọrọ yìí múlẹ̀ ninu atẹjade kan , ṣungbọn ko sọ iye ọmọ wẹwẹ to wa ninu wọn.
Ọjọru ni ile naa da wo ni agbeegbe Ita Faaji, Lagos Island ni Isalẹ Eko.
Awọn oṣiṣẹ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri atawọn adoola si gbyanju lati doola ẹmi awọn ti ijamba naa ba.
Ni owurọ ọjọ Ẹti ni awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Eko bẹrẹ si ni wo àwọn ile ti ko dara ni adugbo naa.
Ìròyìn tó ń tẹ̀ wa lọ́wọ́lọ́wọ́ ní wí pé ilé alájà mẹta náà ni ilé ìwé alakọbẹrẹ kan wà nínú rẹ̀ ní agbègbè Ita faji ipinlẹ Eko.
A gbọ iroyin pe ile iwe alakọbẹrẹ yii lo wa loke patapata ile alaja ọhun. Bakan naa, iroyin sọ pe awọn akẹkọọ ti ha sabẹ ile naa.
awọn oṣiṣẹ ile iṣẹ pajawiri atawọn adoola ẹmi ti wa nibi iṣẹlẹ naa.
Bakan naa, ikọ oniroyin BBC Yoruba naa ti n ko iroyin jọ.













