Deji Adeyanju sọ ìdí tó fi kúrò nínú ẹgbẹ́ "Our Mumu don Do''

Oríṣun àwòrán, Adeyanju
Osù Kejila ọdun 2018 ní Deji Adeyanju ti àwọn ènìyàn mọ si ajàfẹ́tọ́ ènìyàn àti ọ̀kan lára àwọn alátilẹyìn ẹgbẹ ajafẹtọ "Our Mumu don Do" lọ si ẹwọn lóri ẹsun pé ó lọ́wọ́ sí ìpàniyan kan pé yóò ṣi wà lẹ́wọn titi dí osù keji ọdun yíì ní Ipinlẹ̀ Kano.
Sùgbọ́n lẹ̀yìn ti Deji Adeyanju pàdà dé láti ẹwọn ló kọ ọ́ sori àtẹjiṣẹ́ twitter rẹ̀ pé òun kò ṣe atìlẹyìn fún ''Our Mumu don Do" mọ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Sí àwọn ọmọ Nàìjíríà,
Mó ti kọ̀wé láti ma jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ''Our Mumu don Do". Mí ò ni ìgboyà nínú adari ẹgbẹ́ náà Charley Boy. Ó dalẹ̀ èróngbà ìpínú ìdì ti wọn fi da ẹgbẹ́ náà fi sílẹ̀ pẹ̀lú bo se lọ pa ìdí àpò pọ̀ pẹ̀lú àwọn aninilára nígbà ti mo lọ si ọgbà ẹwọ̀n.
ÌDÍ TI MO FI "OUR MUMU DON DO SILẸ̀"
Ilé iṣẹ́ BBC Yorùbá bá Deji Adeyanju sọ̀rọ̀ lórí ìdí to fi fi ẹgbẹ́ "Our Mumu don Do", ó si sàlàyé pé adarí ẹgbẹ́ náà Charles Oputa tí gbogbo ènìyan mọ̀ si Charley boy ti gbẹ̀yìn bẹbọ jẹ́ fun ẹgbẹ́ náà nítori ìdì èyí, òun kò lè tẹ̀síwájú nínú ẹgbẹ́ ọ̀hun. O fí kun àlàyé rẹ̀ pé àsìkò ọ̀rọ̀ kò tii tó láti sàlàyé lẹ́kunrẹ́rẹ́ ohun ti Charley boy ṣe nigba ti òun wà lọ́gbà ẹwọ̀n.










