Governorship Election Update: Àfikún ìdìbò yóò wáyé nìpínlẹ̀ mẹ́fà lọ́jọ́ kẹtàlélógún oṣù yìí

Awọn eeyan n bere fun ki ajọ INEC yanju ọrọ idibo

Oríṣun àwòrán, OTHER

Àkọlé àwòrán, Awọn eeyan n bere fun ki ajọ INEC yanju ọrọ idibo
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ajọ eleto idibo lorilẹede Naijiria, INEC ti kede ọjọ kẹtalelogun gẹgẹ bi ọjọ ti afikun idibo yoo waye lawọn ipinlẹ mẹfa ti idibo gomina ko tii pari.

Ọga ajọ INEC to n ri si eto iroyin ati ilanilọyẹ, Ọgbẹni Festus Okoye lo fọrọ naa lede lẹyin ipade to ṣe pẹlu awọn lọgalọga ajọ INEC lori ibo gomina to waye lọjọ Abamẹta to kọja.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

O ṣalaye pe yoo waye nipinlẹ Adamawa, Bauchi, Benue, Kano, Plateau ati Sokoto ati ni gbogbo ibudo idibo ti ibo ile igbimọ aṣofin naa ko ti kẹsẹ jari kaakiri orilẹede Naijiria.

Àkọlé fídíò, 'Amosun ṣiṣẹ́ l'Ogun ṣùgbọ́n kí Dapo ma yà wá'

Ọgbẹni Okoye ni ajọ INEC yoo kede l'Ọjọru ni kikun awọn ẹkun ati ibudo idibo ti afikun idibo yii yoo ti waye.

O ṣalaye pe idibo gomina ko niyanju lawọn ipinlẹ mẹfa nitori rogbodiyan to bẹ silẹ lawọn ibikan, dida lilo ẹrọ kaadi idibo duro ati wi pe ajọ INEC gan an kuna lati ko ẹrọ kaadi idibo de awọn ibudo idibo kan.

Ọga INEC sọ pe ajọ naa ko le kede ẹni to jawe olubori lawọn ipinlẹ tọrọ kan yii lai ṣe afikun idibo gẹgẹ bi ofin to de eto idibo ni Naijiria ti sọ.

O ni ajọ INEC yoo tun ṣepade lati jiroro lori ọrọ idibo gomina nipinlẹ Rivers ti ajọ naa da duro lẹyin ti rogbodiyan bẹ silẹ kaakiri ipinlẹ naa.