Governorship Election Updates: Ìdí tí ìdìbò kò fi yanjú láwọn ìpínlẹ̀ kan lórílẹ̀èdè Nàìjíríà
Ibeere ti awọn eeyan wa n beere bayii gan ni pe ki gan ni Inconclusive tí ajọ INEC n kede bayii pe o n fa idiwọ ti ko fi si ẹni ms gomina awọn ipinlẹ kan lorilẹede NAijiria?
yii ati pe ki lo n faa idibo ti kii yanju lorilẹede Naijiria bii ti igba kan?
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Idi kan ṣoṣo ni ajọ INEC fi lee kede pe idibo ko yanju ni ibi kan eyi to si lee faa ti wọn ko fi ni kede olubori nibẹ.
Gẹgẹ bii abala kẹrindinlọgbọn abadofin eto idibo INEC, ajọ INEC ko lee kede ẹni to jawe olubori bi iye ibo ti wọn ba wọgile ba pọ to eyi to ṣi lee ni ipa lara abajade idibo ọhun.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iyẹn ja si pe bi iye ibo ti wọn wọngile ba ps ju iye ibo to ya oludije to lewaju ati eyi to tẹ lee lọ, wọn yoo kede idibo bẹl pe ko tii yanju ni.
Fun apẹrẹ bi iye ibo ti ẹni to ṣe ipo kinni ba fi n la ẹni to wa ni ipo keji ba jẹ ọgọrun, iye ibo ti wọn ba wọgile ko gbọdọ ju mọkandinlọgọrun lọ.
Ni kete ti iye ibo ti wọn wọgile ba ti ju mọkandinlọgọrun lọ, INEC yoo kede ibo bẹẹ 'Inconclusive' ni. Iyẹn jasi pe ibo bẹẹ ko yanju.
Idi ni pe o ṣeeṣe ki gbogbo awọn oludibo to le ni mọkandinlọgọrun, ti wọn wọgile naa dibo fun ẹni to n ṣe ipo keji ki o si tipasẹ bẹẹ pada wa ṣe ipo kinni.
Pẹlu eyii atundi ibo gbọdọ waye laaarin ọjọ mọkanlelogun.
Ọrọ awọn amofin lori rẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Amofin Mohammed Fawẹhinmi to ba BBC News Yoruba sọrọ ṣalaye pe aikun oju oṣunwọn ajọ eleto idibo INEC lo faa ti ọrọ idibo ti ko yanju fi wa di tọrọ fọnkale.
O ni lootọ ofin daabo bo ajọ INEC lori ikede ibo ti ko yanju ṣugbọn gẹgẹ bii ọrs rẹ, ka ni ajọ INEC ṣe iṣẹ rẹ bii iṣẹ ni ọrọ yii ko ni ri bẹẹ.














