Governorship Election Updates: PDP Kwara fèsì lórí àgbéǹde ìwádìí ìdigunjalè Ọffa

Abdulrahman Abdulrazaq

Oríṣun àwòrán, Abdulrahman Abdulrazaq

Ẹgbẹ oselu PDP nipinlẹ Kwara ti fesi lori ikede kan ti gomina ti wọn sẹsẹ dibo yan nipinlẹ kwara, Abdulrahman Abdulrazaq sọ pe, oun yoo tun iwadi se lori isẹlẹ idigunjale to wale nilu Offa lọdun to kọja.

Atẹjade kan ti akọwe ipolongo fẹgbẹ oselu PDP nipinlẹ Kwara, Tunde Ashaolu fisita salaye pe, o daju pe Abdulrazaq ko ni imọ to lori isẹlẹ idigunjale to waye nilu Ọffa.

Ashaolu ni " Niwọn igba ti a mọ pe agbara wa lọwọ gomina lati yan oun ti yoo jẹ isejọba rẹ logun, sugbọn gbolohun to jade lẹnu gomina tuntun ti wọn dibo yan nipinlẹ Kwara fihan pe, ohun mẹta kan n sẹlẹ si.

Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí:

Ọhun akọkọ lo sọ pe, boya gomina tuntun ko mọ nkankan nipa bi idigunjale nilu Ọffa se waye ni, tabi ki wọn ma salaye bi ọrọ naa se jẹ gangan fun gomina tuntun.

Ekeji ni pe koo seese ki Abdulrazaq ma mọ bi wọn ti n se iwadi iwa ọdaran ati ilana igbẹjọ tabi ko jẹ pe oun gangan n pe aja ni ọbọ funra rẹ, to si fẹ bẹrẹ eto isejọba rẹ nipa dida omi alaafia eto oselu ru.

Ara awọn afurasi adigunjale Ọffa

Oríṣun àwòrán, @PoliceNG

"Eyikeyi ko wu ko jẹ, awa ọmọ ẹgbẹ oselu PDP nipinlẹ Kwara yoo jẹ ki Abdulrazaq mọ pe, ileesẹ ọlọpa ilẹ wa ni ẹkunrẹrẹ iwadi lọwọ, nipa bi idigunjale ilu Ọffa ti lọ, ti wọn si ti fi abajade iwadi wọn ransẹ si agbefọba to wa nileesẹ agbẹjọro agba ilẹ wa, ni igba meji ọtọọtọ."

"Ninu abajade iwadi kinni ati ikeji, o foju han pe agbefọba naa ko fi epo bọ iyọ, to si ni funfun nẹnẹ ni ọwọ aarẹ ile asofin agba ilẹ wa, Bukọla Saraki ati gomina ipinlẹ Kwara to wa lori aleefa bayii, Abdulfatai Ahmed mọ."

Bukola Saraki

Oríṣun àwòrán, @bukolasaraki

Ẹgbẹ oselu PDP ni, oun wa fẹ kede faraye pe, ninu isẹ akọse gomina tilu sẹsẹ dibo yan nipinlẹ Kwara, idunkooko mọni, idẹrubani, ati didọdẹ ẹni lo kọkọ rawọle.

PDP ni dipo ki Abdulrazaq sọrọ lori ilana ti yoo gba sejọba to durore, n se lo n fihan araye pe, ifẹsẹmulẹ alaafia nipinlẹ Kwara ko si lara ohun to mumu laya ijọba oun.