Wo bí àwọn ọmọ Amẹ́ríkà ṣe ń sọ èdè Yorùbá bí ẹni ń jẹ ẹ̀kọ
Awọn akẹkọọ orilẹede Amẹrika kan ti gunlẹ si ilu Ibadan.
Ohun ti wọn wa fun jẹ eyi to ya ọpọ lẹnu – kikọ ede Yoruba!
Lasiko ti ọpọ obi ni ilẹ Yoruba kii fẹ ki ọmọ wọn sọ ede Yoruba mọ afi ede Gẹẹsi, awọn oyinbo gan an lo wa n lepa ati sọ ede Yoruba bayii.
Oru to n mu ni Naijiria kọja ti ilẹ Amẹrika lọpọlọpọ - Kennedy
Nigba ti wọn n sọrọọ lori iriri wọn, Kennedy Odiboh ni ayipada oju ọjọ to yatọ si ti Amẹrika ti wọn ti n bọ ni ipenija oun.

O ni igba ti oun de, oun ṣakiyesi pe oru pọ yatọ si orilẹede Naijiria.
Bi mo ba sun mo n laagun, bi mo ba n rin, bi mo ba ṣe ohunkohun, mo n laagun.
Mo ti pade ifẹ - Kayla

Lara awọn akẹkọọ ọhun ni Kayla Ifasanmirowa. O ṣalaye pe fun oun o, ẹkọ ede Yoruba loun wa kọ, amọṣa o dabi ẹni pe irinajo kadara lo ja si fun oun.
Kayla ni oun ti ri ifẹ ni Naijiria bayii, oun si ti n ronu lori boya ki oun kuku duro ti ollolufẹ oun lorilẹede Naijiria.

“Mo pade ololufẹ mi ni Naijiria, mo n ro o boya ki n duro ni Naijiria, ṣugbọn mi o tii mọ.”
Awọn akẹkọọ naa ni awọn ti rin irinajo kaakiri lọ si awọn ilu bii Abẹokuta, Ilesha Osogbo
Bakan naa ni wọn ni awọn kọ nipa aṣa, iṣe, ounjẹ ati ọpọlọpọ.













