Obìnrin tó ba Eniola Badmus lórúkọ jẹ́ lórí Tiktok rí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́ta he

Eniola Badmus

Oríṣun àwòrán, Eniola Badmus/Instagram

Arabinrin kan, Nwakaego Okoye, ti gba idajọ ẹ̀wọ̀n ọdun mẹta, fun ẹsun pe o tọpinpin gbajumọ òṣèré, Eniola Badmus, lori ayelujara.

Onidajọ Nicholas Oweibo ti ile ẹjọ́ giga ijọba apapọ to wa ni agbegbe Ikoyi niluu Eko lo ṣe ìdájọ́ naa lori ẹ̀sùn meji ti wọn fi kan Nwakaego.

Ninu ẹ̀sùn ti wọn fi kan arabinrin naa, wọn ni Nwakaego ati ẹnikan to n jẹ Chimabia (to ti sá lọ bayii) da ọ̀ràn naa laarin oṣu Kejila, ọdun 2022 si oṣù Keje, ọdún 2023, nipinlẹ Eko.

Iwe ẹsun naa ṣàlàyé pe igbesẹ wọn tako abala 24(1)(b)(2)(a)(c) ati 27 ninu ofin to wà fun lilo ayelujara, ti ọdun 2015.

Arabinrin Eniola Badmus fi ọlọpaa mu Nwakaego Okoye nitori pe o sọ àwọn ọ̀rọ̀ ibanilorukọ jẹ nipa rẹ lori ayelujara Tiktok.

Iroyin sọ pe obinrin naa sọ pe Badmus ma n ṣe akojọpọ àwọn ọ̀dọ́bìnrin fun awọn oloselu fun ibalopọ.

Ṣugbọn nigba ti ọwọ ọlọpaa tẹ ẹ, Okoye jẹwọ pe oun ba Eniola Badmus lórúkọ jẹ́ nitori pe ọrẹ oun kan ṣèlérí ẹgbẹrun lọ́nà igba Naira fun oun.

Saaju idajọ ile ẹjọ́, ni fidio kan ti kọ́kọ́ jade si ori ayelujara, to ṣe afihan bi Okoye ṣe n bẹ Eniola, pe oun nílò owo lati san owó ilé, lo mu ki oun hu iru iwa bẹẹ.

Ninu idajọ rẹ, Onidajọ Oweibo fun Arabinrin Okoye ni anfaani lati san ẹgbẹrun lọ́nà àádọ́jọ Naira dípò ẹ̀wọ̀n ọdun mẹ́ta.

Ìgbésẹ̀ naa waye nitori pe arabinrin náà fihan nílé ẹjọ́ pe oun kabamọ iwa tó hù.

'Èèyàn ẹlẹ́ran ara ni àwa gbájúmọ́ náà jẹ́'

Lẹyin idajọ naa, Eniola Badmus to fi aworan kan si oju opo Instagram rẹ̀ ní nnkan to buru ni ibanilorukọ jẹ.

Ninu aworan naa ni Arabinrin Badmus ti duro niwaju ile ẹjọ́ giga ti igbẹjọ naa ti waye.

O ni ọpọ igba ni lawọn eeyan ma n sọ orisirisi nnkan buruku nipa oun lori ayelujara, paapaajulọ nigba ti oun ṣi lomi lara pupọ ati lasiko ipolongo ibo to kọja nitori oludije to gbe si lẹyin

"O kò mọ mi rí, ṣùgbọ́n o lọ si ori ayelujara lati ma a sọ àwọn nnkan ti kii ṣe otitọ nipa mi lai ni ẹ̀rí kankan."

Badmus sọ pe eniyan ẹlẹran ara ni awọn ilumọọka pẹlu jẹ gẹgẹ bíi gbogbo eniyan yooku , to si má n ni imọlara nnkan ti wọn ba ṣe tabi sọ si wọn.

" Ọ̀pọ̀ eeyan ni iru àwọn ọrọ buburu yii ti fun ni ibanujẹ ati irẹwẹsi ọkàn."

O ni lootọ ni ominira ọ̀rọ̀ sisọ wà, sugbọn eeyan gbọdọ má a ṣọ́ ọ̀rọ̀ sọ nitori ipa buburu to le ni lara ẹlòmíì.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post