Ẹ fún wa lọ́jọ́ méje láti yanjú ọ̀rọ̀ yìí - Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àpapọ̀ rọ NLC

Aworan Sẹnetọ Ali Ndume

Oríṣun àwòrán, Google

Akojanu ile igbimọ asofin agba lorilẹede , Sẹnetọ Ali Ndume ti ni ki awọn olori ẹgbẹ osisẹ NLC ati TUC lati fun wọn lọsẹ kan lati yanju gbogbo ibeere ẹgbẹ osisẹ fun ijọba apapọ

Saaju ni a ti mu wa yii pe awọn olufẹhonuhan yabo ile igbimọ asofin lati fi ẹhonu wọn si ijọba lẹyin ti wọn yọ owo iranwọ epo bẹntiro ati awọn igbesẹ mii, eyi ti wọn ni pe o n fiya jẹ pupọ awọn ọmọ Naijiria .

Lara awọn ibeere ẹgbẹ osisẹ ni pe ki da iye epo bentiro pada si ibi o se wa tẹlẹ, ki wọn si fowo kun owo oṣu awọn osisẹ.

Ndume ni abadofin ti wa ni ile asofin to n pe fun atunse ileesẹ tomn pese epo bentiro, eyi ti yoo fopin si bi ijọba se n gbe epo lọ oke okun.

O rọ awọn olufẹhonuhan lati fun ile igbimọ asofinn ni ọsẹ kan lati yanju gbogbo ibeere wọn.

"Ẹ fi ọkan to ile igbimọ asofin nitori a mọ nnkan to lọ lorilẹede wa,

"A ni lati fọwọsowọpọ lati mu itẹsiwaju ba orilẹede nitori a ni ọpọlọpọ isoro to n ba wa finra.

"Sugbọn mo n fi da yin loju pe a yoo gbe igbesẹ lori iwe ti ẹ kọ fun wa yii."

A ò le máa ṣiṣẹ́ bi erin kí á máa jẹ ìjẹ èlérí-Ayuba Wabba

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹgbé àwọn òṣìṣẹ́ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà péjọ sí gbọ̀ngán Unity Fountain nílùú Abuja, Olú ìlú orílẹ̀-èdè Nàíjíríà, láti fi ẹhonu hàn sí Ìjọba lori ẹ̀tọ́ wọn ti Ìjọba kọ lati fún wọn

Ààrẹ Ẹgbé àwọn òṣìṣẹ́ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ rí, Ayuba Wabba sọrọ, ó ké sí ìjọba láti dá sí ọrọ to wa nilẹ yii, àwọn naa ni ẹbí, ará, idile ti àwọn yoo toju, àwọn o le ma fi gbogbo ipá wọn ṣiṣẹ ti ko si owó nínú, Ó ní ẹ jẹ kí àwọn ti o lowo lọwọ mi

Lẹyin ti wọn kuro ni Unity Fountain, ibi ti wọn pejọ si, wọn kọ rí si ilé Igbimọ Aṣofin lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà ní bí ti wọn yóò ti ba àwọn asoju ilé Igbimọ Aṣofin sọrọ lori oun ti àwọn fẹ lọwọ Ijọba.

Ọ̀gbẹ́ni Joe Ajaero ti o jẹ ààrẹ tuntun fún ẹgbé àwọn òṣìṣẹ́ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà kà àwọn oun ti wọn fẹ, O ni àwọn fẹ ki wọn san owó oṣu mẹjọ ti wọn jẹ àwọn olukọ fafiti, ki wọn wa nkan ṣe si ọrọ epo rọ̀bì, kí wọn mu inu àwọn Oṣiṣẹ dùn ni pa sísan owo oṣu dédé,àti bẹẹ bẹẹ lọ

Lẹ́yìn èyí, agbẹnusọ fún ilé Igbimọ Aṣofin lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Tahir Monguno síì bawọn sọrọ, o rawọ ẹbẹ si wọn, o si ni, ki wọn fún Ìjọba ni Ọjọ méje lati fi wa nkan ṣe si ọrọ naa, ṣugbọn ti àwọn ba kọ lati ṣe atunṣe, ki awọn oṣiṣẹ ṣe oun to ba wu wọn,

Hajiya Ireti Heebah Kingibe, sẹnatọ obinrin niluu Abuja naa si fikún pé ko ni ju ọsẹ kan lọ, ki wọn ni gbagbọ ninu wọn, o ni àwọn jọ wa ninu rẹ ni, àwọn yóò si ri da ju pe àwọn ja fún ẹtọ àwọn oṣiṣẹ

Wo bí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ NLC ṣe fìpá já lẹ̀kùn ilé aṣòfin àpapọ̀ Nàìjíríà lásìkò ìwọ́de

Awọn oṣiṣẹ fi ipa ja lẹkun wọle

Awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ to n ṣe iwọde ni olu ilu Naijiria, Abuja ti fi ipa ja ilẹkun wọle si ile igbimọ aṣofin apapọ Naijiria to wa nilu Abuja.

Awọn oṣiṣẹ n ṣewọde lori bi gbogbo nnkan ṣe wọngogo lorilẹede Naijiria latari awọn igbesẹ atunto ọrọ aje ti ijọba to wa lode bayii lorilẹede Naijiria n gbe, paapaajulọ yiyọ owo iranwọ ‘subsidy’ ori epo.

Awọn oṣiṣẹ naa bẹrẹ iwọde wọn lati gbagede Unity fountain nilu Abuja nibi ti wọn ti gbera lati lọ fi ẹhonu wọn to awọn aṣofin apapọ leti.

Amọṣa nigba ti wọn de gbagede ile aṣofin apapọ, titipa gbọingbọin ni wọn ba iloro ile aṣofin naa.

Eyi lo mu ki wọn fi tipatikuuku ja lẹkun onirin naa wọle ti wọn si ya bo gbagede naa.

Awọn oṣiṣẹ fi ipa ja lẹkun wọle