Wo ibí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ NLC ṣé ń ṣe ìfẹhonúhàn àti Ìyanṣẹ́lódì lónìí

Aworan Iwọde

Awọn osisẹ kaakiri orilẹede Naijiria bẹrẹ iwọde ati ifẹhonuhan loni kaakiri ipinlẹ mẹrẹrindinlogoji ati olu ilu Naijiria Abuja.

Lara ohun ti wọn n bere fun ni pe ki ijọba fopin si gbogbo rogbodiyan ti awọn ọmọ Naijiria n la kọja lẹyin ti ijọba yọ owo iranwọ bentiro.

Saaju ni Aarẹ Bola Tinubu ti kede awọn igbesẹ ijọba apapọ lati mu idẹrun ba awọn Naijiria lasiko ọwọn gogo yii sugbọn awọn ẹgbẹ osisẹ ni ko ki n se nnkan ti awọn eeyan fẹ lati ọwọ ijọba.

Lati olu ilu orilẹede Naijiria, Abuja lọ awọn ipinlẹ bi Eko, Ọyọ, Ogun, Kano, Osun, Abia, Rivers ati awọn ipinlẹ mii ni ogunlọgọ awọn osisẹ labẹ ẹgbẹ osisẹ NLC ati TUC ni wọn tu sita lati fẹhonuhan si ijọba

Lọjọ isẹgun ni egbẹ naa sọ pe ọrọ aarẹ kii ṣe esi taraalu lero ati wi pe ko jọ pe ọrọ yi mọ riri iru inira ati ijiya ti araalu n farada.

Wo awọn ipinlẹ to kopa ninu ifẹhonuhan naa

Ipinlẹ Eko

Aworan awọn olufẹhonuhan

Nipinlẹ Eko, iwọde waye lagbegbe Ikẹja nibi ti awọn olori ẹgbẹ osisẹ ti pejọ si ọfisi gomina ti wọn si mu orin ẹhonu loriṣiriṣi bọ ẹnu.

Awọn olori naa ni ikilọ ṣi ni igbesẹ ti awọn n gbe lọwọ bayii ati pe bi ọrọ naa ba de oju rẹ tan, o ṣeeṣe ki awọn yawọ agboole ti ijọba ba kọ lati ba awọn sọrọ

Sun kẹrẹ fakẹrẹ ti gba gbogbo oju popo ti awọn ẹsọ alabo si wa nilẹ lati mojuto ifẹhonuhan naa lati ma di tọrọfọkale

Ipinlẹ Rivers

Aworan iwọde lati ipinlẹ Rivers

Niluu olu ilu ipinlẹ Rivers, Port Harcourt, awọn olufẹhonuhan gbera lati ileeṣẹ wọn lọ si ofisi gomina ti wọn si n ke pe Gomina lati kesi Aarẹ Bola Tinubu.

Alaga NLC ni Rivers, Alex Agwanwa ni se koko ki ijọba se atunse si awọn ileeṣẹ to n se epo rọbi ati wọn gbọdọ fi owo kun owo oṣu awọn oṣisẹ

Ipinlẹ Oyo

Aworan iwọde lati ipinlẹ Oyo

Ṣáájú ìfẹ̀honúhàn tó ń lọ lọ́wọ́ jákèjádò orílẹ̀èdè yìí ni àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀honúhàn ti wọn. Láti bíi ọjọ́ mẹ́ta sẹ́yìn sì ni wọ́n ti sọ agádágodo sí ẹnu ìloro ọ́fìsì ìjọba níbi tí Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ náà tí ń ṣíṣe.

Bótilẹ̀ jẹ́ wí pé Gómìnà tí rán àwọn aṣojú láti pẹ̀tù sí àwọn òṣìṣẹ́ náà. Ariwo tí wọ́n mú bọ ẹnu ni pé Gómìnà gan an ni àwọn fẹ́ rí.

Ipinlẹ Ogun

Aworan iwọde lati ipinlẹ Ogun

Aago meje aarọ oni ni awọn ọmọ ẹgbẹ NLC korajọ si ile ẹgbẹ wọn to wa ni agbegbe Lẹmẹ, Abẹokuta ipinlẹ naa lati bẹrẹ iwọde wọn.

Bẹ o ba gbagbe, Ọjọru, Wẹsidee to kọja ni ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ NLC ni Naijiria kede pe àwọn yoo bẹrẹ iyanṣẹlodi, bi ijọba ko ba wa nnkan ṣe si ọrọ owo iranwọ ori epo ti wọn yọ.

Nigba to n sọrọ, alaga ẹgbẹ naa n'ipinlẹ Ogun laarọ oni, Kọmureedi Hammẹd Benco Ademọla ṣalaye pe iya naa ti pọ ju fun wọn, awọn ko si le maa gi ara da a mọ.

Lati ile ẹgbẹ wọn ni wọn ti n lọ kaakiri ilu Abẹokuta lati jẹ ko ye ijọba apapọ pe iyanjusi patapata l'awọn n fẹ.

Ipinlẹ Osun

Aworan iwọde nipinlẹ Osun

Ni agbegbe Olaiya ni awọn osisẹ ti bẹrẹ ifẹhonhan nipinlẹ Osun ti wọn si rọ Ijọba apapọ ati ijọba ipinlẹ Osun lati wa ojutu si bi iya se n jẹ awọn osisẹ ati awọn ọmọ orilẹede Naijiria ni apapọ.

Egbẹ́ òṣìṣẹ́ yóò bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀honúhàn àti Ìyanṣẹ́lódì lónìí

Aworan NLC ati TUC

Oríṣun àwòrán, NLC

Lonii, ẹgbẹ oṣisẹ lorilẹede Naijiria yoo bẹrẹ ifẹhonuhan ati iyansẹlodi lati fi tako igbesẹ ijọba apapọ lati yiyọ owo iranwọ epe bẹntiro ati awọn igbesẹ ijọpa apapọ mii.

Lọjọ Ajẹ, Aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Ahmed Tinubu ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ, to kede igbesẹ ijọba lati mu aye dẹrun fun araalu

Sugbọn ẹgbẹ osisẹ ọrọ Aarẹ kọ lati salaye ọna to fẹ fi mu adikun ba bi nnkan se le lasiko yii fun awọn ọmọ Naijiria.

Ni pataki aarẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ Comrade Ajaero ni ọrọ awọn ileeṣẹ ifọpo Naijiria to dẹnukọlẹ ati atunṣe wọn lawọn lero pe aarẹ yoo sọ nipa rẹ.

''Ibẹrẹ gbogbo wahala yiyọ ẹkunwo taa n ri yi ko ṣẹhin aiṣẹ awọn ileeṣẹ ifọpo Naijiria.O ṣeni laanu pe lati oke de ilẹ ọrọ aarẹ Tinubu ko mẹnu ba atunṣe awọn ileeṣẹ ifọpo yi rara ati rara''

Ki ni nnkan ti NLC n bere fun

O to nnkan mẹfa ti ajọ ẹgbẹ n bere lọwọ ijọba apapọ orilẹede Naijiria

  • Mimu adehun to wa laarin ijọba apapo ati osisẹ wa si mumu sẹ
  • Dida owo iranwọ bentiro pada, ati mimu adikun ba ọwọn gogo owo epo bentiro
  • Sise atunse si awọn ileeṣẹ to n se epo bentiro ni Warri, Kaduna ati Fatakwal
  • Sisan owo oṣu mẹjọ fun awọn olukọ fasiti