Governorship Election Updates: Ajimọbi gba Makinde nimọran lati gbaradì fún iṣẹ́ ńla

Oríṣun àwòrán, Abiola Ajimobi
Gomina ipinlẹ Ọyọ, Abiola Ajimọbi ti ki gomina ti ilu sẹsẹ dibo yan, Onimọ ẹrọ Seyi Makinde ku oriire pe o jawe olubori ninu idibo gomina to kọja.
Ninu iwe ikini ku oriire naa ti Ajimọbi kọ, eyi ti oludamọran rẹ feto iroyin, Bọlaji Tunji fisita, lo ti gba Makinde nimọran pe nibayii ti eto idibo ti tan, yoo dara ko ko gbogb o awn eeyan tọrọ kan nidi isejọba ipinlẹ Ọyọ mọra ninu ijọba rẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Seyi Makinde làwa ń bá lọ lọ́jọ́ Satide - Ladọja
- Bí mo ṣe ń tako Buhari bá ìjọba tiwantiwa mu - Ọbasanjọ
- Ìbò sáà kẹta fún Ajimọbi ni ìbò Adelabu, ẹ yàgò fun - Seyi Makinde
- Níbo lowó ìrànwọ́ ẹ̀kọ́ wa wà - Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Kwara ń bèèrè?
- Ọbasanjọ ni ọmọ òrùkàn tó di olóri orílẹ̀èdè lẹ́ẹ̀mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀
- Àwòdamiẹnu àwòrán rèé nílé àwọn olùdíje tó wọ́lé ìbò
Ajimọbi tun rọ gomina tilu sẹsẹ dibo yan ọhun lati bẹrẹ si ni gbaradi fun isẹ nla to wa niwaju rẹ, ko si gbagbe gbogbo awọn ohun to sẹlẹ lasiko idibo, bẹẹ lo ni ko rọ awọn alatilẹyin rẹ lati dẹkun sisọ awọn ọrọ to lee tun da wahala silẹ nipinlẹ Ọyọ.

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde
"Lati ọdun mẹjọ sẹyin, a ri daju pe ofin fẹsẹ mulẹ, ti idagbasoke ati agbega si ba ipinlẹ Ọyọ lati ipasẹ awọn aseyọri to fojuhan, gẹgẹ bawọn mẹkunnu labẹle ati awujọ agbaye ti n sọ."
"Ni bayii ti mo n ki ọ ku oriire, mo gbadura pe wa se aseye ti alakan n se epo, mo si rọ ọ pe ko gbajumọ awọn eto idagbasoke ti mo ti se ni ẹka ipeese alaafia, eto aabo ẹmi ati dukia ti awọn araalu ti jẹ anfaani rẹ lati ọ̀dun mẹjọ sẹyin."








