Oyo Election: ADP, ZLP SDP fa ọwọ́ Seyi makinde sókè bíi gómìnà wọn

Sẹnetọ Rashidi Ladọja fa ọwọ Seyi Makinde soke

Apapọ awọn ẹgbẹ oṣelu alatako nipinlẹ Ọyọ ṣe akanṣe ipade awọn akọroyin, lati kede atilẹhin wọn fun Oludije si ipo gomina ipinlẹ Ọyọ ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, Onimọ-ẹrọ Ṣeyi Makinde.Ipade naa waye lọjọ Iṣẹgun ni olu ile ẹgbẹ awọn akọroyin to kalẹ si Iyaganku niluu Ibadan.Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lara awọn eeyan pataki to peju-pesẹ sibi ipade naa ni gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹri, Oloye Rashidi Ladọja, awọn oludije si ipo gomina nipinlẹ Ọyọ ninu ẹgbẹ oṣelu ADC, ZLP, ati SDP.

Lara awọn oludije gomina tẹlẹ to wa nibẹ ni Sẹnetọ Olufẹmi Lanlẹhin, Oloye Sharafadeen Alli ati Oloye Bolaji Ayọrinde ni ṣisẹ-n-tẹle.

Awọn ẹgbẹ oselu to n se atilẹyin fun Seyi Makinde

Awọn ẹgbẹ naa kede atilẹhin wọn, bẹẹ si ni wọn fi igbagbọ wọn han wi pe, oludije fun ipo gomina ipinlẹ Ọyọ ninu ẹgbẹ ọṣelu PDP, Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde ni yoo jawe olubori ninu eto idibo ọjọ Abamẹta.