Ó tó gẹ́ ní àṣà ìpolongo tó fakọyọ lásìkò ìbò 2019

Oríṣun àwòrán, @RealAARahman
Lagbo oṣelu,ti awọn oloṣelu ba fẹ ṣe koriya fun awọn alatilẹyin wọn, wọn a máa fun wọn ni awọn ọrọ akọmọna eleyi ti yoo ma da wọn laraya.
Eyi ti yoo si maa fi rinlẹ lọkan wọn pe ki wọn dibo fun ẹgbẹ oṣelu tiwọn.
Lasiko idibo gbogboogbo Naijiria eleyi ti o ku abala keji yi, awọn ọrọ akọmọna kan dagboro ru ti wọn si ko ipa ribi ribi ninu oṣelu lawọn ipinlẹ kan.
Ni meni meji, a o ma gbe awọn ọrọ wọn yi wo ati iru ipa ti wọn ko lasiko idibo aarẹ to kọja.
Ó tó gẹ́!
Nilu Ilorin ni aṣa yi ti bẹrẹ ti o si ṣe atọkun bi ifidirẹmi gbajugbaja oloṣelu ọmọ ilu naa, Bukola Saraki ati ẹgbẹ PDP ti ṣe waye.
Akọmọna Ó to gẹẹ gaan ni akawe kan gbogi to ṣe apejuwe bi ọrọ akọmọna ti ṣe lagbara lati ṣe iwuri fun awọn oludibo.

Oríṣun àwòrán, @RealAARahman
Bi wọn ba ti ṣe n lọgun oto gẹẹ, bẹ ni awọn oludibo lọmọde ati lagba yoo ma dahun pe ''Lilọ lẹ lọ.''
Ninu awọn akọmọna, pupọ eeyan lo gbagbo pe o to gẹẹ lo fakọyọ.
4+4= Next Level
Aarẹ Muhammadu Buhari lo fun ara rẹ jan aṣa ipolongo yi lontẹ nigba ti o lọ si iwaju ile asofin Naijiria lati gbe aba isuna ọdun 2019 kalẹ.
4+4 ko ni ṣe pupọ pẹlu ọrọ bi kii ṣe nina ika mẹrin owo mejeeji soke lati fi han pe lẹyin ọdun mẹrin ti APC lo ni ijọba,wọn yoo lo mrin miran si.

Oríṣun àwòrán, @kekeTony
Aṣa yi gbalẹ laarin awọn alatilẹyin APC ti awọn ọmọ ogun kan ati ọlọpaa naa si ba wọn da ninu aṣa naa.
Take it Back
Awọn ọdọ Naijiria ni wọn ni aṣa yi ti Omoyele Sowore ti ẹgbẹ AAC ṣagbatẹru rẹ. Ni ṣoki, ohun to tun mọ si ni ''gba a pada''.

Oríṣun àwòrán, @Sowore2019
Awọn alatilẹyin rẹ a ma lo akọmọna yi lati fi ipinu wọn rinlẹ nipasẹ gbigba ijọba pada lọdọ awọn agbaagba oloṣelu ti wọn ti wa lori oye ti pẹ.
Akọmọna yi gbiyanju amọ omi pọju ọka lọ fun un nito ri pe Sowore ko ri ijọba gba pada lọwọ Muhammadu Buhari ti o pegede ninu ibo aarẹ 2019.
Atikulated
Latara orukọ oludije ipo aarẹ fun ẹgbẹ oṣelu PDP ni wọn ti da aṣa ipolongo Atikulated kalẹ.
Aṣa naa lalẹ ti awọn olorin kọọkan naa tun sọ di akọmọna ti awọn ọmọ gbẹ PDP n kọ kaakiri.
Wọn fi orukọ igbakeji Atiku, Peter Obi naa kun ti wọn si n dawọn laṣa pọ pe Atikulated Obi-diently.

Oríṣun àwòrán, @Atiku
#Otogelagos
Ẹda O to gẹ̀ẹ́ ti Kwara ni #Otogelagos eleyi ti o ti n gbalẹ diẹ diẹ.
Kete ti Ibrahim Oloriegbe yẹ aga nidi Sẹnetọ Saraki pẹlu atilẹyin o to gẹẹ ni awọn kan nilu Eko naa bẹrẹ #Otogelagos.
Koda, awọn ipade ati iwọde kan waye ni ilu Eko ti ọpọlọpọ eeyan si lọdi wọn mọ adape ọrọ yii to ti gbẹnu awọn kan ni ipinlẹ Eko.













