Election Update 2019: ‘Ìgbìmọ̀ amúsẹ́yá APC pàṣẹ lọ rọọ́kún nílé fún Amosun, Okorocha

Oríṣun àwòrán, Facebook/Senator Ibikunle Amosun/Governor Rochas O
Iroyin to n tẹwa lọwọ ni pe ẹgbẹ oṣelu APC ti paṣẹ lọ rọọkun nile fun awọn Gomina Ibikunle Amosun ti ipinlẹ Ogun ati Rochas Okorocha ipinlẹ Imo.
Igbimọ amuṣẹya ẹgbẹ naa lo daba yii lẹyin ipade wọn ti o waye nilu Abuja.
Lanre Issa Onilu to jẹ akọwe ipolongo ẹgbẹ naa ni lootọ ni ẹgbẹ gbe igbesẹ ọhun amọ awọn ṣi n ṣiṣẹ lori atẹjade lori ọrọ naa.
Igbesẹ ẹgbẹ yi tako ohun ti wọn ti sọ saaju nipa awọn Gomina wọn yi wi pe awọn ko ni ijiya kankan lati fi jẹ wọn lori awọn iwuwasi wọn to jọ bi ẹni tako aṣẹ ẹgbẹ.








