APC: Ọ̀rọ̀ àbùkù látẹnu Okorocha ń ta ẹrẹ̀ bá ẹgbẹ́ wa

Rochas Okorocha

Oríṣun àwòrán, @ImoGovernor

Àkọlé àwòrán, Okorocha ni alága ìgbìmọ̀ àwọn gómínà APC tẹ́lẹ̀

Nkan kò lọ déédé láàrín ìgbìmọ̀ aláṣẹ ẹgbẹ́ òṣèlú APC àti Gomina Ìpínlẹ̀ Imo, Rochas Okorocha, lórí àwọn ọ̀rọ̀ kan tí wọ́n ní ó ń tẹnu rẹ̀ jáde.

Atẹ̀jáde kan láti ọwọ́ alukoro ẹgbẹ́ òsèlú APC, Bolaji Abdullahi, sọ pé, lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí ni Okorocha ń sọrọ àbùkù sí ẹgbẹ́ nàá, àwọn àgbààgbà ẹgbẹ́ àti alaga wọn, Olóyè John Odigie-Oyegun lórí ìdìbò abẹ́le tí ó wáyé ní oṣù karùń-un ní ìpínlẹ̀ Imo.

Okorocha, tó jẹ́ alága ìgbìmọ̀ àwọn gómínà APC ni wọ́n ní ó lo ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kan tí orúkọ rẹ̀ ńjẹ́ Ireagwu Obioma láti gbé àtẹ̀jáde kan jáde tí ó fẹ̀sùn oríṣiríṣi kan ẹgbẹ́ APC.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn òǹwòye ní, ọ̀rọ̀ náà jẹ àbùkù fún ìṣọkan APC nítori ipò tí Okorocha wà nínú ẹgbẹ́ nàá láti ilẹ̀ wá.

Rochas Okorocha àti Odigie Oyegun

Oríṣun àwòrán, @ImoGovernor

Àkọlé àwòrán, APC ní àwọn kò ní gba ọ̀rọ̀-kọ́rọ̀ láàyè nínú ẹgbẹ́ náà

Atẹ̀jáde ẹgbẹ́ náà tilẹ̀ fi ẹ̀sùn kán pé, o gbé ìwé kan jáde nínú èyí tí wọ́n lo ayédèru orúkọ àwọn olọ́yè ẹgbẹ́ nàá méjì - Edwin Ikhinmwin àti amòfin agbà Muiz Banire.

Ẹgbẹ́ APC ní, àwọn kò ní gba ọ̀rọ̀-kọ́rọ̀ láàyè nínú ẹgbẹ́ náà o. Wọ́n wa rọ Okorocha láti kó ara rẹ̀ ní ìjánu, kí ó sì wá ọ̀nà àlàáfíà pẹ̀lú àwọn àgbààgbà ẹgbẹ́ náà.