Okorocha: Ọ̀rọ̀ aláàrẹ̀ wà lẹ̀nu Oyegun, alaga APC

Rochas Okorocha ati John Oyegun

Oríṣun àwòrán, @APCNigeria

Àkọlé àwòrán, Wàhálà tó ń bẹ́ sílẹ̀ lágbo òṣèlú APC ti ń kọ àwọn eeyan lominu; pàápàá láàárín Oyegun àti Gómìnà Okorocha

Wahala n kun wahala lẹgbẹ oṣelu APC, o si ti n di egbinrin ọtẹ ti ọkan n ru soke bi a ṣe n pakan.

Ko pẹ yii ti ariwo rukerudo sọ laarin ẹgbẹ oṣelu APC to n ṣejọba lorilẹede Naijiria; eyi ko si tii jo lọlẹ ti aye tun gbọ ariwo ija agba meji laarin ẹgbẹ oṣelu APC.

Alaga apapọ ẹgbẹ oṣelu APC, John Oyegun ati Rochas Okorocha to jẹ alaga igbimọ awọn gomina ipinlẹ labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu APC ni wọn n gbena wo oju ara wọn bayii.

Rochas Okorocha ati John Oyegun

Oríṣun àwòrán, @APCNigeria

Àkọlé àwòrán, Oyegun ni ogun afọwọfa lo n ja Gomina Okorocha

Idi wahala wọn ko si ṣẹyin abajade idibo abẹnu ẹgbẹ oṣelu naa eleyii ti Gomina Okorocha ni awọn alagbara kan laarin ẹgbẹ oṣelu naa n lo lati yọ ọwọ oun lawo bi nkan ṣe n lọ si lẹgbẹ oṣelu naa, papaajulọ , ni ipinlẹ Imo.

Kato wi kato fọ, alaga ẹgbẹ oṣelu naa, John Oyegun ni iroyin sọ pe o da gomina Okorocha lohun ọrọ rẹ ni kia pe ko ṣẹri pada sile lọ yẹ ara rẹ wo lati mọ ibi ti bata ti n taa lẹsẹ.

Ninu ọrọ Oyegun, ogun afọwọfa lo n ja Gomina Okorocha nitori ninu iwoye rẹ awọn igbesẹ gomina ipinlẹ Imo naa lo n mu kawọn eeyan rẹ o kọ ipakọ sii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba to wa n ba BBC sọrọ, amugbalẹgbẹ fun fun Gomina Ipinlẹ Imo, Rochas Okorocha lori ọrọ ibanisọrọ ayelujara, Ebere Nzewuji ni ọrọ ti Jọhn oyegun n sọ ko ta leti awọn eeyan ipinlẹ naa 'to mọ pataki iṣẹ ti Gomina Okorocha ti gbe ṣe nibẹ.'

"Ọrọ alaarẹ ni John Oyegun n sọ. Ikanra kikuna to kuna lati ri anfani alaga apapọ ẹgbẹ oṣelu APC gba lẹẹkeji ni oloye Oyegun fẹ fi mọ gomina Okorocha."