Ọ́dọ́ Kwara fẹ̀hónú hàn fún pípe Saraki láti jẹ́jọ́

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹgbẹ́ oríṣi meji ti fẹ̀hónú hàn lórí ọ̀rọ̀ Saraki ti wọn ni kó wá káwọ́ pọ̀nyìn rojọ́. Àparò kan kò gbọdọ̀ ga ju ìkejì lọ
Ẹgbẹ́ ọ̀dọ́ kan ní ìpínlẹ̀ kwara,Youth Agitator Nationalist Forum ti wọ́de ìfẹ̀hónú han fún pípe ààrẹ àgbà ilé ìgbìmọ́ aṣofin, Bukola Saraki, láti wá káwọ pọ̀nyìn rojọ́ lóri ìdigun jalè Ọfa.

Nínú àtẹ̀jáde kan ti àgbẹnusọ ọlọ́pàá Moshood Jimoh, gbé jáde ní ọjọ́ Aìkú ni wọn ti sọ pe márùn-ún nínú àwọn adigun jalè ti ọwọ ṣìnkún àwọn ọlọ́pàá tẹ̀ ló sọ pé Bukọla Saraki mọ̀ sí ohun tí àwọn ń ṣe.
'Ẹ jẹ ki ọlọpaa ṣiṣẹ wọn'
Ohun to kọ iwaju sẹni kan ni ọrọ ohun, ẹyin lo kọ si ẹlomii.
Awọn Association of Concerned Ọfa Indigenes Home and Abroad nilu Ofa naa wọde lati ile iwe LGEA Iyẹru ọkin koja lọ si Ibrahim Taiwo road lọ si Idi Ogun.
Awọn n ṣe iwọde pe awon faramọ pe ki awọn agbofinro ṣiṣẹ wọn bi o ti yẹ nitori pe ìbí kò gbọdọ̀ ju ìbí
Àmọ́ṣá, àwọn ọdọ́ tó ń wọ́de ìfẹ̀hónú hàn ọ̀hún lọ sí ilé Ọlọ́fà ti ìlú Ọffa Ọba Mufutau Gbadamosi ní ìjọba ìpínlẹ̀ Ọfa pé kí àwọn ọlọ́pàá má kí òṣèlú bọ ọ̀rọ̀ ìwádìí ìdijalè tó wáyé níbẹ̀
Ààrẹ ẹgbẹ́ ọ̀hún Peter Kayode sọ pé ó kéré tan àwọn yóò kó ẹgbẹ̀rún márùn-ún ọ̀dọ́ jọ tí yóò rìn ìpínlẹ̀ Kwara lọ sí ìlú Àbújá láti fí ìfẹ́ àwọn han sí Saraki













