L'Ábẹ́òkúta,Ẹlẹ́wọ̀n 68 kẹ́kọ̀ gboyè iṣẹ́ ọwọ́

Ọga agba ileeṣẹ ọgba ẹwọn lorilẹede Naijiria, Ja'afaru Ahmed

Oríṣun àwòrán, @npsreformer

Àkọlé àwòrán, Ileesẹ ọgba ẹwọn fẹ yi oju ti awujọ fi n wo ẹlẹwọn pada

Awọn ẹlẹwọn mejidinlaadọrin lo ti kẹkọo gboye ninu iṣẹ ọwọ naa bayii lọgba ẹwọn Ibara nilu Abẹokuta.

Awọn iṣẹ ọwọ ati iṣẹ ọna bii aṣọ riran, irun ṣiṣe, gbẹnagbẹna, aṣọ hihun, ilẹkẹ sisin, pẹlu ọṣẹ ṣise wa lara awọn iṣẹ ti awọn ẹlẹwọn naa ti kẹkọọ gboye.

Igbakeji ọga agba ileesẹ ọgba ẹwọn nipinlẹ Ogun to n ṣakoso ọgba ẹwọn naa, Sunday Kolawole, ṣalaye pe ara igbesẹ lati tun aye awọn ẹlẹwọn naa ṣe eleyi to ni ọga agba ileeṣẹ ọgba ẹwọn lorilẹ-ede Naijiria, Ja'afaru Ahmed, la kalẹ ni eto naa jẹ.

Awọn ohun elo ẹkọṣẹ ọwọ

Oríṣun àwòrán, @npsreformer

Àkọlé àwòrán, Iléeṣẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n ní ara ọ̀nà láti yí ojú tí àwùjọ fi ń wo ẹlẹ́wọ̀n ni ẹ̀kọ́ṣẹ́ náà jẹ́

Bakan naa lo ni agbekalẹ iṣẹ ọwọ fawọn ẹlẹwọn wa lara awọn ọna ti ileeṣẹ naa n yẹ lati rii pe ayipada de ba oju ti awujọ fi n wo ẹlẹwọn.

Ọga ẹlẹwọn, Sunday Kọlawọle, ni laarin oṣu mẹrin si ọdun mẹta ni awọn ẹlẹwọn naa fi kọ iṣẹ wọn ti wọn si mọ ọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni "ọgba ẹwọn kii ṣe ibudo ifiyajẹni bikoṣe ibudo atunṣe aye awọn ti wọn wa sibẹ ki awọn pẹlu lee di eniyan rere lawujọ."