Nigeria vs Czech Republic: Mikel ní Eagles ṣetán fún Czech

Oríṣun àwòrán, @mikel_john_obi
Balogun ikọ̀ Super Eagles, John Obi Mikel, ti fi dá àwọn ọmọ Naijiria loju pe dídùn lọsàn ìdíje òní yóò so.
Mikel ni gbogbo ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles ti wa ni sẹpẹ bayii lati koju ikọ Czech Republic ninu ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹsọrẹ ti wọn fi n gbaradi fun idije ife ẹyẹ agbaye FIFA ni orilẹ-ede Russia.
Ni ọsan ọjọru ni ikọ Super Eagles ati Czech Republic yoo maa ta kangbọn nilu Vienna, l'orilẹ-ede Austria.

Oríṣun àwòrán, @mikel_john_obi
Mikel Obi ni lootọ Super eagles fidirẹmi ninu ifẹsẹwọnsẹ wọn pẹlu ilẹ Gẹẹsi ṣugbọn igbesẹ nla lo jẹ fun ikọ Super eagles lati mọ bi wọn ṣe gbewọn si.
Lori opo twitter rẹ, @mikel_john_obi o dupẹ lọwọ awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria atawọn ololufẹ Super eagles lagbaye.
"Idanwo nla ni latọwọ ikọ to lagbara-a n tẹsiwaju si ifẹsẹwọnsẹ to kan."








